Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gbajugbaja oloṣelu kan niluu Idanre, Ọgbẹni Akinlabi Akinnasọ lawọn ẹsọ alaabo yinbọn pa nibi ti wọn ti n ka ibo ni Ọwẹna – Ayetoro, niijọba ibilẹ Idanre, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Oloogbe ọhun tọpọ awọn eeyan mọ si Oluọmọ ni wọn lo kagbako iku airotẹlẹ latari ede aiyede kan to bẹ silẹ laarin oun atawọn ẹṣọ alaabo to n mojuto eto idibo agbegbe naa.
Oluọmọ la gbọ pe ibọn ṣeesi ba lasiko to doju ija kọ awọn ẹṣọ alaabo ọhun nigba tawọn oṣiṣẹ ajọ eleto-idibo fẹẹ fun ẹni to jawe olubori ninu eto idibo sileegbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnarebu Festus Akingbasọ (Fessy West) ni iwe-ẹri ‘mo yege’.
Ọkunrin oloṣelu ọhun ni wọn ti gbe oku rẹ lọ si mọsuari ọsibitu ijọba to wa niluu Idanre, nibi ti wọn tọju rẹ si ni gbogbo igba ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.
Fessy West to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn kede orukọ rẹ pe o yege lati lọọ ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Idanre ati Ifẹdọrẹ nileegbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, ti ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to wa nibẹ lọwọ, iyẹn Ọnarebu Tajudeen Adefioye ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Small Alhaji, si fidi-rẹmi.