Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Iku ojiji ti pa ọkan lara awọn ajafẹtọọ ọmọniyan to kẹkọọ gboye ni Yunifasiti ipinlẹ Eko, LASU, Yusuf Nurudeen, ẹni tawọn eeyan mọ si Ọmọ mẹwaa.
Awọn agbebọnrin kan ni wọn yinbọn fun Ọmọ mẹwaa lalẹ Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ yii. Nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa ni awọn agbebọn naa kọ lu Ọmọ mẹwaa ati ẹni keji rẹ ti wọn jọ wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ, Majek, toun naa jẹ oṣiṣẹ ni LASU.
Ibi olobiripo marosẹ LASU-Iba la gbọ pe awọn to kọ lu wọn ti da wọn duro, ti wọn yinbọn mọ awọn mejeeji, ṣugbọn kinni naa ba Yusuf Nurudeen ju ẹni keji ẹ lọ. Iku lo ja si fun un, nigba ti Majek ṣeṣe ni tiẹ, to si n gbatọju ni ọsibitu lọwọ. Ile igbokuu-si ọsibitu Mainland, l’Ekoo, ni wọn gbe oku Oloogbe Yusuf si.
Lọjọ to ku ọla to maa ku, Ọmọ mẹwaa lọ sinu ọgba LASU to ti kẹkọọ gboye lọdun 2019, awọn akẹkọọ naa si fi tayọtayọ ki i kaabọ, nitori wọn ni ajafẹtọọ awọn akẹkọọ ni ọkunrin naa n ṣe. Ẹka imọ nipa abojuto iwe lo ti ṣetan nileewe ọhun, wọn si ni ọrọ awọn akẹkọọ maa n mumu laya rẹ gan-an.
Ọmọ mẹwaa dije dupo olori awọn akẹkọọ LASU ri, ko kan wọle ni, ṣugbọn eyi ko din ifẹ rẹ fun ileewe naa atawọn akẹkọọ ku, iyẹn ni iku to pa a yii ṣe n ka gbogbo wọn lara, ti wọn si n sọ pe awọn ko mọ awọn amookunṣika to ba ohun to dun jẹ bii eyi.