Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkùnrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Tunde Akinmoyewa, lo ti pade iku ojiji pẹlu bi ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ ṣe yinbọn lu u nibi to ti n dan oogun ayẹta ti wọn ṣẹṣẹẹ ṣe fun un wo labule kan ti wọn n pe ni Láòṣò, lagbegbe Lájé, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Aje, Mọnde ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.
ALAROYEgbọ pe ọmọ babalawo ni Tunde, oun pẹlu ọrẹ rẹ kan ti wọn n pe ni Bọde, ni wọn jọ lọọ ṣoogun ayẹta lọdọ oniṣegun kan, bi awọn mejeeji ṣe n dele ni wọn ti sare mu oogun yii, ti Tunde si gbe ibọn le ọrẹ rẹ lọwọ lati kọkọ dan kinni naa wo lara oun.
O ṣe ni laaanu pe ewe sunko fun ọmọkunrin to ṣẹṣẹ tẹwọn de ọhun, nitori pe bo ṣe yinbọn ọhun lo dahun lara rẹ lẹyẹ-o-sọka, ti ọmọkunrin yii si digbo lulẹ, lo ba ku patapata.
Loootọ lawọn to wa nitosi sare gbe ọkunrin ti wọn lo jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun lọ sileewosan kan to wa nitosi ninu abule naa, nibẹ ni wọn ti fidi rẹ mulẹ fawọn to gbe e lọ pe o ti ku ki wọn too gbe e debẹ.
Gbogbo akitiyan awọn ẹṣọ alaabo lati ri Bọde to yinbọn pa ọrẹ rẹ mu lo ja si pabo nitori loju-ẹsẹ to ti mọ pe ọrọ ti yiwọ lo ti sa lọ, ti ko si sẹni to mọ ibi to wọlẹ si latigba naa.
A gbọ pe ọdun ogun to fẹẹ waye niluu Ondo loṣu Kẹsan-an, ni oloogbe ọhun ati ọrẹ rẹ ṣe lọọ ṣoogun ayẹta nitori itu buruku ti wọn fẹẹ pa lasiko naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni ibọn ti Tunde ṣẹṣẹ lọọ ra lo fẹẹ dan wo ti Bọde ọrẹ rẹ fi ṣeeṣi yinbọn lu u.
O ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lati ri ọkunrin to ti sa lọ naa mu, ko le waa jiya to tọ labẹ ofin. Wọn ti tọju oku Tunde si mọṣuari ile-iwosan ijọba to wa niluu Ondo.