Yahaya Bello ti wa latimọle EFCC, eyi ni obitibiti owo ti wọn lo ko jẹ

Monisọla Saka

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Onidaajọ Maryanne Anenih, ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ ilu Abuja, paṣẹ pe ki wọn fi Yahaya Bello, ti i ṣe gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, sinu ahamọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede yii, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC).

Yahaya Bello atawọn meji kan, Shuaibu Oricha ati Abdulsalam Hudu, ni ajọ naa ka ẹsun oriṣii mẹrindinlogun si lọrun.

Awọn ẹsun bii ipawọ-pọ huwa ọdaran, dukia kiko jọ lọna ti ko bofin mu atawọn iwa to lodi sofin mi-in ni wọn fi kan wọn.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeeji, Joseph Daudu to ṣoju fun Bello ati Kẹmi Pinheiro, to jẹ agbẹjọro fun ajọ EFCC, ni Adajọ Anenih, sun igbẹjọ si ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun yii.

Bello ti ile-ẹjọ ti bẹrẹ igbẹjọ rẹ, ti wọn si reti pe ko yọju latinu oṣu Kẹrin, ọdun yii, lo deede yọ si awọn EFCC lolu ileeṣẹ wọn to wa ni Jabi, l’Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Bo ṣe yọju si kootu lọjọ Wẹsidee yii ni yoo jẹ igba akọkọ rẹ nile-ẹjọ, latigba ti ajọ naa ti wọ ọ lọ siwaju adajọ.

Oun atawọn meji ti wọn fẹsun kan yii, ti wọn jẹ olujẹjọ kin-in-ni ati olujẹjọ keji, bẹbẹ niwaju adajọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Ẹsun owo to to aadọfa biliọnu Naira o le, ni wọn fi kan Yahaya Bello. Ṣaaju akoko yii, iwaju Onidaajọ Emeka Nwite ni wọn wọ Bello lọ, nitori biliọnu mẹrinlelọgọrin Naira, ti wọn lo ko jẹ lapo asunwọn ipinlẹ Kogi, lasiko to n ṣe gomina ipinlẹ naa.

Ninu ẹsun ti wọn ka si wọn lọrun ni wọn ti ni Bello atawọn meji ọhun ṣe owo ilu mọkumọku, ti wọn si ra dukia loriṣiiriṣii. Lara rẹ ni ile oni ẹẹdẹgbẹrun miliọnu ataabọ (950 million), ti wọn ra si 35, Danube street, Maitama District, Abuja. Bakan naa ni oni ọgọrun-un miliọnu Naira to wa ni Nọmba 1160, Cadastral Zone C03, Gwarimpa II District, Abuja, ati eleyii ti wọn ra si Nọmba 2, Justice Chukwudifu Oputa Street, Asokoro, Abuja, toun naa jẹ ẹẹdẹgbẹrun ati ogun miliọnu Naira, atawọn dukia mi-in bẹẹ.

Wọn tun fẹsun kan wọn pe wọn fi owo to din diẹ ni ẹgbẹta Dọla ($570,330) ati eyi to le diẹ ni ẹẹdẹgbẹta ataabọ Dọla ($556,265), ranṣẹ sinu ile ifowopamọsi TD Bank, lorilẹ-ede Amẹrika, ati awọn dukia ti wọn ko jọ lọna aitọ, to fi mọ owo to le ni ẹgbẹta miliọnu Naira (668.8 million), lati ileeṣẹ Bespoque Business Solution Limited.

Daudu, ti i ṣe agbẹjọro fun Bello, waa beere fun beeli fun onibaara rẹ, niwaju adajọ, amọ Kẹmi Pinheiro ta ko beeli naa. O ni latinu oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni anfaani rẹ lati gba beeli ti kasẹ nilẹ.

Daudu fesi pe, “Beeli kan ṣoṣo ti a n beere fun ni ti olujẹjọ akọkọ, ti i ṣe Yahaya Bello, ti wọn ti gbe siwaju ile-ẹjọ lọjọ kejilelogun, oṣu yii.

Oluwa mi, bakan naa ni wọn fi adirẹsi sinu iwe beeli ti wọn kọ ọhun.

“Ẹri aritọkasi kin-in-ni, ti i ṣe yiyọju si gbagede kootu ṣe pataki, bi olujẹjọ si ṣe yọju si kootu lonii fi han pe o ni ibọwọ fun ofin”.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ofin orilẹ-ede yii fidi ẹ mulẹ pe eeyan ti ko mọwọ mẹsẹ ni olujẹjọ, afigba ti kootu ba fidi ẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Daudu tun sọrọ siwaju si i pe lara ẹtọ onibaara oun ni lati wa ni ominira ara ẹ lasiko to n gbaradi fun igbẹjọ.

Ṣugbọn agbẹjọro ijọba tun ta ko beeli ti wọn fẹẹ gba fun olujẹjọ keji, o ni oṣiṣẹ ijọba to ṣi n ṣiṣẹ gẹgẹ bii adari agba nile ijọba ipinlẹ Kogi lọwọ bayii ni, ati pe o ṣee ṣe ko tun tun iru iwa bẹẹ hu.

Daudu naa fesi pada pe oun ko fara mọ ọrọ pe o le tun iru iwa arufin bẹẹ hu, nitori wọn ko ti i ri i ko ṣe e lẹyin ti wọn ba fun un ni beeli.

O ni ọrọ ti agbẹjọro ajọ EFCC sọ yii ko lẹsẹ nilẹ, nitori ko fi han pe eeyan to maa n figba gbogbo huwa arufin ni olujẹjọ.

Lẹyin naa ni Onidaajọ Anenih sun igbẹjọ si ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, lati le dajọ lori beeli ti wọn n wa fawọn olujẹjọ, bẹẹ lo pa a laṣẹ pe kawọn olujẹjọ mẹtẹẹta ṣi wa lakata ajọ EFCC, titi di asiko igbẹjọ tuntun.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Yahaya Bello fẹsẹ ara ẹ rin wọnu olu ileeṣẹ EFCC to wa ni Jabi, niluu Abuja, pẹlu awọn ẹṣọ alaabo rẹ.

Owuyẹ kan lati ileeṣẹ EFCC to kọkọ fidi ọrọ naa mulẹ sọ pe Gomina Usman Ododo, to wa nipo nipinlẹ Kogi lọwọ bayii ko tẹle ọga rẹ wa gẹgẹ bo ṣe ṣe ninu oṣu Kẹsan-an, ti wọn ranṣẹ pe Bello.

Aimọye igba ti ẹjọ kan an niwaju adajọ ni Bello ko yọju, lati inu oṣu Kẹrin, ọdun yii to ti yẹ ko ṣe bẹẹ.

Bakan naa ni wọn naka aleebu si Gomina Ododo, fun bo ṣe n fẹyin pọn ọn, to si n lo ofin imuniti gomina to wa nipo lati daabo bo ọga rẹ ọhun lọwọ ijọba.

 

Leave a Reply