Faith Adebọla
B’adiẹ da mi loogun nu, ma fọ ọ lẹyin, ti ọmọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ibrahim Yayah to n ṣiṣẹ ọkọ ero ṣe, eyi to mu ko gun Kabiru Abdullahi lọbẹ lọrun, tiyẹn si gbabẹ ku ti sọ ọ dero atimọle ọlọpaa bayii. Ẹsun ipaniyan ni wọn tori ẹ mu un, ko si ti i sẹni to le sọ ohun ti yoo tidi ọran to da yii yọ fun un.
ALAROYE gbọ pe ọmọ ẹyin ọkọ ni awọn mejeeji, ṣugbọn gareeji ọtọọtọ ni wọn ti n ṣiṣẹ. Kabiru Abdullahi n ṣiṣẹ ni ọja Ọtọ, ni Oyingbo, niluu Eko, nigba ti Ibraim Yahya n ṣiṣẹ tiẹ ni gareeji ọkọ kan ti wọn n pe ni Kanuri Motor Park, to wa ni Ebute-Mẹta.
Gareeji yii naa ni wọn wa lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun yii, ti ede aiyede fi ṣẹlẹ laarin wọn. Nibi ti wọn ti n gba ọrọ naa laarin ara wọn bii ẹni gba igba ọti ni wọn ti kọju ija sira wọn.
Ibunu ti ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nilẹ lo ru bo Kabiru loju, lo ba yọ ọbẹ jade, o si fi gun Ibahim lori.
N niyẹn ba fibinu kuro nibẹ, o lọọ tọju ara rẹ. Ṣugbọn ipadabọ Abija ni Ibrahim fi ọrọ naa ṣe lọjọ keji to pada si gareeji naa. Ko too kuro nile lo ti mu ọbẹ asooro kan dani, nigba to si foju kan Kabiru, niṣe lo da ọbẹ ọhun de e lọrun, o gun un. N ni ẹjẹ ba bẹrẹ si i tọ jade lara ọmọkunrin yii.
Awọn to wa nitosi ni wọn sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Ebute, ṣugbọn awọn dokita sọ pe ọmọkunrin naa ti ku ki wọn too gbe e de ọdọ awọn.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ṣalaye pe loootọ ni iṣẹlẹ naa waye. O ni, ‘‘Ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji yii ni wọn waa fẹjọ sun lagọọ ọlọpaa pe ni nnkan bii aago meji aabọ ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ọmokunrin kan, Kabiru Abdullahi to n ṣiṣẹ ni ọja Ọtọ, ni Oyingbo, niluu Eko, gun Ibraim Yahya ti oun n ṣiṣẹ ni gareeji ọkọ ni Kanuri, lọbẹ ni ori lasiko ti ede aiyede ṣẹlẹ laarin wọn.
‘‘Ṣugbọn nigba to di nnkan bii aago meji aabọ ọjọ keji, Kabiru naa lọọ gbẹsan, lo ba gun Yahya lọbẹ nibi ọrun, awọn to wa nitosi sare gbe e lọ si ọsibitu, ṣugbọn ọmọkunrin naa pada ku’’.
O fi kun un pe awọn ti mu Kabiru, iwadii si ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.