Faith Adebọla, Eko
Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa ti sọ fun gbajugbaja adẹrin-in poṣonu oṣere tiata ilẹ wa nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa pe ko tete maa gbaradi fun ẹsun ifipabanilopọ mi-in, yatọ seyii to n jẹjọ rẹ lọwọ, wọn lawọn maa too wọ ọ lọ sile-ẹjọ laipẹ.
ASP Wahab Kareem lo sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, yii, nile-ẹjọ kan to n gbọ ẹsun akanṣe ati iwa iṣẹkuṣe, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Kareem lo ṣoju fun ileeṣẹ ọlọpaa Eko gẹgẹ bii ẹlẹrii ta ko olujẹjọ naa, Baba Ijẹṣa lo n jẹ ẹjọ lọwọ lori ẹsun pe o fipa ba ọmọọdun mẹrinla kan laṣepọ lẹẹmeji, akọkọ, nigba tọmọ naa wa lọmọọdun meje, ati nigba to di ọmọọdun mẹrinla, ko too di pe wọn ri i mu.
Lasiko to n ṣalaye abọ iwadii tawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ṣe lori ẹjọ yii nigba ti Baba Ijẹṣa fi kọkọ wa lakata wọn ni Panti, Yaba, Kazeem ni ọmọbinrin mi-in toun forukọ bo laṣiiri tun yọju lasiko naa to fẹsun kan afurasi ọdaran yii pe o fipa ṣe ‘kinni’ foun nigba toun wa lọmọọdun mejila.
“A fọrọ wa ọmọbinrin naa ati Baba Ijẹṣa lẹnu wo, ọmọbinrin naa si ko o loju, ṣugbọn afurasi ọdaran yii sẹ kanlẹ, o loun kọ.
‘‘Ọmọ ọhun ṣalaye pe adugbo Agah, lagbegbe Ikorodu, niṣẹlẹ naa ti waye, a si tẹle ọmọ naa ati Baba Ijẹṣa lọ si ile ti wọn sọ, lanlọọdu ile ọhun, Alaaji Jameel, si fidi ẹ mulẹ pe ile oun ni Baba Ijẹṣa n gbe lasiko naa, o naka si yara ẹ, ṣugbọn Baba Ijẹṣa ni wọn purọ mọ oun ni.”
Kareem ni Baba Ijẹṣa ṣi maa jẹjọ lori ọrọ yii.
Bakan naa lo ṣafihan fidio kan ti wọn fi gba ọrọ ti Baba Ijẹṣa sọ lọdọ awọn ọlọpaa silẹ fun Adajọ Oluwatoyin Taiwo. Ninu fidio naa ni afurasi ọdaran yii ti sọ pe: “Mo halẹ mọ ọn loootọ, mo fọwọ kan an, mo di i lọwọ mu, mo si pọn ika ẹ la.”
Kareem ni oun nileeṣẹ ọlọpaa ni koun bojuto ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa yii latari bi olufisun rẹ, Damilọla Adekọya, tawọn eeyan mọ si Princess, ṣe ṣaroye pe ẹnikan wa lara awọn to n gbọ ẹsun yii to jẹ ọrẹ timọtimọ fun Baba Ijẹṣa.
Adajọ ti sun igbẹjọ to kan si ọjọ kejila, oṣu kọkanla, ọdun yii.