Olajide Kazeem
Igbakeji Aarẹ orílẹ̀-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti sọ pe loootọ ni ọpọlọpọ oṣi ati iya n ba awọn ọmọ Naijiria fa a, ati pe ojuṣe ìjọba gidi ni lati tan iṣẹ ati oṣi laarin ilu.
Ilu Abuja ni igbakeji Buhari ti sọrọ yii lẹyin apero ipade ọlọjọ meji laarin awọn aṣofin ati oluṣakoso ninu ijọba.
Ọṣinbajo sọ pe o ṣe pataki ki ẹka eto oṣelu mejeeji yii ṣíṣẹ papọ lati ṣeto tí yoo mu irọrun ba awọn eeyan to dibo yan wọn, bẹẹ ni ko yẹ ki wọn ja araalu kalẹ nigba kan.
O ni ọpọ ohun amayedẹrun ni ko si lónìí ni Naijiria, ti pupọ ninu awọn ogo wẹẹrẹ paapaa ko ri ileewe lọ, ati pe ti ẹka ìjọba to n ṣofin atawọn ti wọn n ṣakoso ilu ko ba ṣiṣẹ papọ, eyi yoo fi wa han gẹgẹ bii ika ati ọdaju ti ko fẹ irọrun fun awọn ti a n ṣejoba le lori.
Igbakeji Aarẹ ti waa rọ awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin atawọn to wa ni ẹka ìṣàkóso ilu lati ṣiṣẹ papọ, ki ojútùú le wa fun oṣi ati iya to n ba awọn ọmọ Naijiria fa a gidigidi.
O fi kun un pe, ounjẹ táwọn eeyan wa maa jẹ, ile ti wọn yoo sun si, aṣọ ti wọn yoo wọ sọrun ati eto ìlera gidi pẹlu bi wọn yóò ti ṣe ran àwọn ọmọ wọn niwee lo jẹ wọn logun, bẹẹ la gbọdọ ṣíṣẹ papọ kí àwọn ohun wọnyi le wà ni arọwọto wọn.
Oloṣelu to ba n ṣe eyi gan-an lo n ṣíṣẹ ilu, to si n wa rere fawọn eeyan ẹ. Ọṣinbajo lo sọ bẹẹ l’Abuja.
Ile mo no ojo sun mole
Yio de ba wa layo loruko EDUMARE