Faith Adebọla
Ọga awọn ṣọja to ṣẹṣẹ kuro nipo laipẹ yii, Ọgagun-fẹyinti Tukur Buratai, ti sọ pe kẹnikẹni ma fọkan si i pe ọrọ eto aabo to mẹhẹ lasiko yii yoo lọ bọrọ, o lo ṣi maa to ogun ọdun ki alaafia too le jọba, iyẹn bijọba o ba kaaarẹ.
Buratai sọrọ ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba to n fara han niwaju awọn aṣofin agba l’Abuja, nibi ti wọn ti n gbe ọrọ rẹ yẹwo fun ipo aṣoju ilẹ wa ti Buhari fẹẹ yan oun atawọn ẹlẹgbẹ rẹ si.
Ọga ṣọja naa sọ pe teeyan ba maa sọrọ sibi tọrọ wa, aipẹ yii lawọn ologun ṣẹṣẹ sunwọn si i lori iṣẹ otẹlẹmuyẹ ati iwadii, o ni latẹyinwa, awọn ki i ri nnkan kan gbọ titi tawọn eeṣin-o-kọ’ku ẹda naa fi maa ṣe akọlu sawọn.
O ni, “Ileeṣẹ ologun nikan ko le da yanju iṣoro aabo to mẹhẹ. O yẹ kawọn nnkan bii ileewosan, ileewe, ọna to ja geere, atawọn nnkan mi-in to maa fihan pe awọn agbegbe wọnyẹn n rọwọ ijọba wa nibẹ, dipo ti gbogbo ẹ kan maa fi jẹ papa ati oko gbalasa lasan.
“Tawọn aaye tẹnikẹni ki i de wọnyẹn ba ṣi wa bẹẹ, ko le rọrun lati ṣẹgun awọn Boko Haraamu, awọn janduku ati awọn agbebọn wọnyẹn, tori wọn aa ṣi maa ribi sa pamọ si.
“Kijọba si to le ṣaṣepari awọn nnkan ti mọ sọ yii atawọn nnkan mi-in to yẹ, ti eto aabo ko ba gbopọn, ki i ṣe ọrọ ọdun kan si meji, aa to ogun ọdun ti ko ba ju bẹẹ lọ.
“Nibi tọrọ de bayii, awọn eeyan buruku ti wọ aarin ilu, ki i ṣe inu igbo nikan ni wọn wa mọ, eyi lo si mu kọrọ naa tubọ ṣoro si i. A maa nilo imọ ẹrọ igbalode ati awọn irinṣẹ to n ba intanẹẹti ṣiṣẹ ka too le bori wọn, ipenija nla si niyẹn fun ijọba.”
Yatọ si Buratai, awọn olori ileeṣẹ ologun yooku ti wọn ṣẹṣẹ fipo silẹ naa wa nibi ijooko ayẹwo ọhun. Lara wọn ni Abayọmi Ọlọniṣakin, Ibok Ekwe, Sadique Abubakar ati Muhammad S. Usman.