Zainab ran awọn ajinigbe si ọmọ aburo ẹ, o fẹẹ fi gba ogun miliọnu lọwọ wọn

Monisọla Saka

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano, ti fi panpẹ ofin gbe obinrin afurasi ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) kan, Zainab Rabiu, nitori bo ṣe lẹdi apo pọ pẹlu awọn ajinigbe mẹta kan lati ji ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹfa to jẹ ọmọ aburo ẹ gbe nijọba ibilẹ Dala, nipinlẹ naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa, to fọrọ naa lede ninu atẹjade to gbe jade l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, ṣalaye pe miliọnu lọna ogun Naira ni Zainab atawọn ikọ to ran niṣẹ beere lọwọ awọn ẹbi ọmọ ti wọn ji gbe, ṣugbọn wọn pada gba miliọnu marun-un le diẹ lọwọ wọn gẹgẹ bii owo itusilẹ.

O ni, “Lọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun yii, iroyin tẹ wa lọwọ lati ọdọ arakunrin kan ni Kofar Ruwa Quarters, ijọba ibilẹ Dala, nipinlẹ Kano, pe wọn ti ji ọmọ oun ọkunrin, Almustapha Bashir, ọmọ ọdun mẹfa gbe, ogun miliọnu Naira ni wọn si n beere fun, ṣugbọn wọn pada gba miliọnu marun-un ati aadọjọ Naira (5,150,000), lọwọ awọn.

“Lasiko iwadii, la ri ọna lati doola ọmọ naa layọ ati alaafia, ti wọn si ri awọn afurasi ọhun mu. Zainab Rabiu, ẹni ọdun marundinlaaadọta, to n gbe lagbegbe Gwammaja quarters, to tun jẹ ẹgbọn baba ọmọ ti wọn ji gbe gan-an lo mu aba ijinigbe yii wa, to si ṣe agbodegba bi wọn ṣe ji ọmọ naa gbe. Oun lo wa awọn eeyan ti wọn ji ọmọ naa gbe.
Awọn yooku ti wọn jọ ṣiṣẹ buruku ọhun ni: Abdurrashid Sa’idu, ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), Hassan Abdullahi, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), ati Ahmed Saleh, ẹni ọdun marundinlọgbọn (25), ti gbogbo wọn n gbe lagbegbe Sheka Quarters, nipinlẹ Kano”.

Kiyawa ni gbogbo awọn afurasi yii ti jẹwọ pe loootọ lawọn ṣe nnkan ti wọn fẹsun rẹ kan awọn, ati pe ni kete ti wọn ba ti pari iwadii, lawọn yoo foju wọn bale ẹjọ.

Leave a Reply