Ṣẹgun ki i ṣe ṣọja, lasiko to wọṣọ ologun lati gba afurasi silẹ lọdọ ọlọpaa ni wọn mu un ni Sango

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣẹgun Ogundeji lo duro bii ṣọja kekere yii, ṣugbọn ki i ṣe ṣọja, ayederu gbaa ni. Koda, tẹwọnde ni paapaa, niṣe lo kan fi igboya wọṣọ ologun lọ si teṣan ọlọpaa Sango Ọta, l’Ọjọruu to kọja yii, o fẹẹ gba afurasi tawọn iyẹn ti mọle silẹ, nibẹ lọwọ palaba rẹ ti segi, ti wọn mu un ṣinkun pe ayederu ṣọja ni.

Lọjọ Wẹsidee naa ti i ṣe ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an yii, Ṣẹgun di kaka ninu aṣọ ṣọja, o de tẹsan ọhun, o si fi igboya beere fun itusilẹ afurasi kan ti awọn iyẹn ti mọle.

Ṣugbọn ọkunrin ologun oju ofurufu kan wa ni teṣan naa, Cpl  John Temitọpẹ lo n jẹ. Ọkunrin naa lo ko Ṣẹgun loju, lo ni iru ṣọja wo ni tiẹ to ri oun gẹgẹ bii ologun ti ko le ki oun ni kiki ologun. Ọrọ naa si pada di ariwo laarin wọn.

Ija to bẹ silẹ laarin wọn naa lo mu DPO teṣan yii, CSP Godwin Idehai, gbọ to fi ni ki wọn wọle wa, lo ba fọrọ wa wọn lẹnu wo. Nibi ifọrọwanilẹnu wo naa lo ti han pe Ṣẹgun ko tiẹ mọ nnkan kan nipa iṣẹ ologun rara, pe ki i tiẹ ṣe ṣọja, o kan wọṣọ ologun lai ki i ṣe ara wọn ni.

Koda, lasiko iwadii naa lo han pe ọkunrin to n pe ara ẹ ni ṣọja yii  ti ṣẹwọn ri, ati pe pipe ara ẹni lohun ti a ko jẹ yii naa lo gbe e dẹwọn nigba yẹn.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti ni ki wọn gbe e lọ sẹka iwadii to lọọrin, ki wọn le ṣeto bi wọn yoo ṣe gbe e lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply