Faith Adebọla
Ki i ṣe tuntun mọ pe ọkan ninu awọn to n gbe fiimu awọn oṣere jade, to si tun jẹ ọmọ jayejaye Eko tawọn olorin fẹran daadaa nni, Ọlajide Kazeem ti gbogbo eeyan mọ si Ṣeun Ẹgbẹgbẹ, ti jade lọgba ẹwọn to ti wa lati nnkan bii ọdun diẹ sẹyin.
Eyi to jẹ tuntun, to si tun ya awọn eeyan lẹnu ni bi wọn ṣe ri ọkunrin naa to pa bibeli mẹgbẹẹ, to si wọ inu ṣọọṣi kan lọ. Niṣe ni ọkunrin naa jokoo laarin awọn ero, toun naa si n tẹti si ohun ti oniwaasu n sọ.
Fidio kan to gba ori ẹrọ ayelujara kan ọhun lo ṣafihan Ṣeun Ẹgbẹgbẹ to wọ aṣọ alawọ eeru kan bayii, to si gbe bibeli mọ ẹgbẹ rẹ. Bẹẹ lo wọnu ọgba ṣọọṣi to ni geeti alawọ dudu ti wọn ko ṣafihan orukọ rẹ yii. Bo ṣe wọbẹ lo jokoo saarin awọn olujọsin.
Ọpọ awọn to ri fidio naa ni wọn n sọ pe ohun to dara ni ọkunrin naa ṣe, nitori ọrọ ọgba ẹwọn ki i ṣe kekere, aja to ba si rele ẹkun to bọ, afi ka ki i ku oriire.
Bẹẹ lawọn mi-in n da awọn to n sọ pe ṣebi Musulumi ni Ẹgbẹgbẹ, ki lo wa lọ si ṣọọṣi lohun pe ki lo kan wọn nibẹ, ko si ibi ti eeyan ko ti le sin Ọlọrun. Ohun to ṣe pataki ni ki ọmọkunrin naa ronupiwada, ko si bẹrẹ si i gbe igbesi aye to daa.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa yii, ni ile-ẹjọ da ọkunrin ọmọ jayejaye Eko to maa n gbe fiimu jade, to si tun jẹ ọrẹ awọn oṣere ati olorinsilẹ pe ko maa lọ sile, lẹyin to lo ọdun meje ati oṣu mẹfa, lọgba ẹwọn.
Ile-ẹjọ giga to wa niluu Ikoyi lo gbọ ẹjọ ọkunrin naa labẹ Onidaajọ Olurẹmi Oguntoyinbo, ti wọn si lo jẹbi ẹsun ẹyọ kan pere, ninu ẹsun bii mẹrinlelogoji ti wọn fi kan an. Ẹsun naa ni wọn gbọ ti wọn fi fun un ni beeli, ṣugbọn ko ri ẹni gba oniduuro rẹ nitori awọn ohun ti adajọ ka silẹ pe o gbọdọ ri ki wọn too da a silẹ.
Adajọ Oguntoyinbo to fagi le mẹtalelogoji ninu awọn ẹsun naa sọ pe wọn ko lẹsẹ nilẹ, nitori ko si ẹri to to lati gbe e lẹsẹ, eyi ni wọn fi ju u sẹwọn. Bakan naa lo ni awọn agbefọba naa ko ni ẹri to to lati gbe gbogbo alaye wọn lẹyin. O tun ni awọn ọlọpaa ti fọwọ kan ninu owo ti wọn tori rẹ mu un. Bẹẹ ni wọn ko ri ẹlẹrii to le fidi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an mu jade. N ladajọ ba sọ ọ sẹwọn ọdun mẹta fun ẹsun ẹyọ kan ti wọn lo jẹbi rẹ.
Ọgba ẹwọn naa lo ṣi wa ti igbẹjọ rẹ fi tun waye ni ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa yii, ti adajọ si tu u silẹ pẹlu awijare pe o ti lo ọdun mẹta ti ẹṣẹ kan ṣoṣo ti wọn tori rẹ ti i mọle pe fun. Eyi ja si pe oṣu mejilelogoji ni ọkunrin to maa n nawo fawọn olorin naa lo ni ọgba ẹwọn ko too gba itusilẹ.
Lojiji ni ariwo deede gba gbogbo ilu pe ọkunrin ti awọn oṣere ki i jinna si nitori bo ṣe maa n nawo fun wọn, tawọn olorin naa si maa n ki i ni mẹsan-an mẹwaa yii ji lphone nileetaja kan n’Ikẹja. Niṣe ni wọn lu ọkunrin naa ti gbogbo oju rẹ wu, ti ẹnu rẹ si bẹjẹ. Ṣugbọn ariwo eleyii ko ti i lọ silẹ ti wọn fi tun ni ọkunrin to ni ileeṣẹ Ebony Productions yii tun lọọ lu awọn Mọla ti wọn n ṣẹ owo Naira si dọla ni jibiti.
Owo Naira ni ọkunrin naa ni oun ni ti oun fẹẹ ṣẹ si tilẹ okeere to fi lọ sibẹ, afi bo ṣe poora mọ wọn loju, to si ji owo wọn gbe sa lọ.
Nigba ti ọwọ tẹ Ṣeun ti wọn gbe e lọ si kootu, awọn Mọla ti wọn n ṣe paṣipaarọ owo ti wọn n pe ni Bureau De Change yii rọ wa sile-ẹjọ ni, ọgọọrọ wọn lo si fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin naa ti lu awọn ni jibiti lọna kan abi omi-in wọn ni aimọye igba lo ti lu awọn ni jibiti, to si poora ki ọwọ too tẹ ẹ yii.
Bii ogoji ninu wọn ni wọn lo ti lu ni jibiti, kaakiri ipinlẹ Eko lọdun 2017 ti wọn mu un. Miliọnu mọkandinlogoji owo Naira, ẹgbẹrun lọna aadọrun-n owo dọla ($90,000), ati ẹgbẹrun mejila ataabọ pọun ni wọn lo lu awọn to n ṣẹ owo yii ni jibiti rẹ laarin ọdun 2015 si 2017. Eyi ni wọn fi ju u sẹwọn lọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2017, ki igbẹjọ rẹ ṣẹṣẹ too waye, ti adajọ si ni ko maa lọ lalaafia, nitori o ti lo kọja ẹwọn ti wọn fẹẹ fun un.