Monisọla Saka
Ọkunrin olorin igbalode to tun jẹ ọmọ bibi onkọrin nla to ti doloogbe nni, Fẹmi Anikulapo Kuti, ti fẹsẹ ara ẹ rin lọọ ba awọn ọlọpaa ni teṣan wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe iwadii ati igbesẹ gbogbo to yẹ ni gbigbe lawọn yoo ṣe gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ lori bi Kuti ṣe fọ ọkan ninu awọn ọlọpaa leti.
Bakan naa ni wọn ni awọn yoo ri i daju pe idajọ ododo lawọn ṣe lori ọrọ naa.
Laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karundinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, sọ ninu atẹjade to fi sita pe Ṣeun ti jọwọ ara ẹ silẹ fawọn agbofinro.
O ni, “Laaaro kutukutu oni ọjọ Aje, ni ọkunrin olorin igbalode ilẹ wa, Ṣeun Kuti, fẹsẹ ara ẹ rin wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, to wa lagbegbe Ikẹja, oun pẹlu agbẹjọro rẹ atawọn aṣoju mọlẹbi wọn.
A si ti fi panpẹ ofin gbe e, ni ibamu pẹlu ofin”.
Agba lọọya nilẹ yii, Fẹmi Falana, to jẹ agbẹjọro fun Kuti, fi awọn lọọya kan nileeṣẹ wọn ranṣẹ gẹgẹ bii aṣoju rẹ lati tẹle Kuti, lasiko to fẹsẹ ara ẹ rin lọọ ba awọn ọlọpaa.
Ninu ọrọ ẹ, Fẹmi Falana ti i ṣe agbẹjọro Kuti ni o ti beere imọran nipa ọrọ ofin lọwọ oun gẹgẹ bii lọọya ẹ, ati pe Ṣeun ni ẹri lati fi wẹ ara ẹ mọ.
O ni, “Emi ni lọọya rẹ, o si ti ṣalaye fun mi. O ni ẹri loootọ. Ki i si i ṣe igba akọkọ niyi toun atawọn ọlọpaa yoo maa ni fa-n-fa”.
Awọn agbofinro waa dupẹ lọwọ awọn araalu lori bi wọn ṣe dide si ọrọ naa, o fi wọn lọkan balẹ pe awọn yoo ṣiṣẹ iwadii naa lai fi epo bọ iyọ, awọn yoo si ṣe e bii iṣẹ, lai fi bojuboju tabi ẹtanu kankan si i, bẹẹ ni awọn yoo dajọ kaluku bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran, to wa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, ni wọn taari Kuti lọ bayii, lẹyin ti wọn ko galagala (ma mu gaari), si i lọwọ, ti wọn si gba bata lẹsẹ rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Ṣeun Kuti ko sinu jọgọdi yii lẹyin ti fọnran kan gba ori ẹrọ ayelujara, nibi to ti fọ ọga ọlọpaa kan to wa lẹnu iṣẹ, ninu aṣọ ọlọpaa lẹgbẹẹ ọna leti lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun yii. Idi to fi gba ọlọpaa yii leti ko ti i han si ẹnikẹni bayii.
Nigba to n sọrọ lẹyin iṣẹlẹ naa, ọkunrin olorin yii ni inu ewu lẹmi oun wa nigba toun fọ ọlọpaa naa leti. O ni ọlọpaa yẹn loun maa pa oun atawọn mọlẹbi oun.
O sọrọ yii, lẹyin ti ọga ọlọpaa patapata nilẹ Naijiria, Usman Baba, paṣẹ pe ki wọn lọ fofin gbe e ni kiakia.
Lẹyin eyi, ni ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ki wọn lọọ fofin gbe Kuti, ki wọn si foju ẹ bale-ẹjọ, nitori ko sẹni to lẹtọọ lati fiya jẹ ọlọpaa to wa ninu aṣọ, ati lẹnu iṣẹ, bo ti wulẹ ki ohun to ṣe dun eeyan to, ni Kuti ba tun gba ori ẹrọ ayelujara Instagram rẹ lọ, o si kọ ọ sibẹ pe, oun ti ṣetan pẹlu wọn lori ọrọ iwadii ati ifọrọwanilẹnuwo, oun yoo si fọwọsowọpọ pẹlu wọn. O loun tun rọ ọga ọlọpaa patapata lati fiya to tọ jẹ ẹni to ba jẹbi lori ọrọ naa.