Monisọla Saka
Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra, ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati ẹsun mi-in to ni i ṣe pẹlu owo Naira lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti kede pe awọn n wa gomina to ṣẹṣẹ kuro nipo nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, nitori ẹsun ikowojẹ.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ajọ yii gbe ikede naa sori ikanni ibanidọrẹẹ Facebook wọn.
Gomina Yahaya Bello ti ajọ EFCC ti wọ lọ siwaju ile-ẹjọ giga ijọba apapọ kan niluu Abuja, to si yẹ ki igbẹjọ rẹ waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin yii, lo kọ ti ko yọju.
Ninu ikede ti wọn gbe soju opo Facebook wọn pẹlu aworan ọkunrin naa ni ni wọn kọ ọ si pe, “A n fi akoko yii fi to araalu leti pe EFCC n wa Yahaya Adoza Bello, ti i ṣe gomina ana nipinlẹ Kogi, eyi ti ẹ n wo aworan rẹ loke yii, nitori ẹsun to ni i ṣe pẹlu kiko owo to le ni ọgọrin biliọnu Naira jẹ (80,246,470,089.88).
“Bello, ọkunrin Ebira, ẹni ọdun mejidinlaaadọta (48), to wa lati ijọba ibilẹ Okenne, nipinlẹ Kogi yii, ni wọn ri gbẹyin ni Nọmba 9, Benghazi street, Wuse Zone 4, Abuja”.
Wọn waa rọ ẹnikẹni to ba ko firi ọkunrin naa, tabi to mọ’bi to fara pamọ si lati kan si ileeṣẹ ajọ EFCC to ba sun mọ wọn kaakiri orilẹ-ede yii.
Nitori bi Yahaya Bello ko ṣe yọju si kootu lasiko igbẹjọ rẹ yii, ni Onidaajọ Emeka Nwite, ko fi ri ohunkohun ṣe ju pe ko sun igbẹjọ rẹ siwaju lọ.
EFCC ni l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, ni awọn oṣiṣẹ awọn gba ile gomina Yahaya Bello to wa lagbegbe Wuse, niluu Abuja lọ, ṣugbọn to jẹ pe gbogbo wakati ti wọn lo nibẹ ti wọn n ṣọ gomina tẹlẹri naa lati le gbe e, wọn ko ri i pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn ikọ ẹṣọ alaabo kan atawọn agbofinro ti wọn duro wawaawa sibẹ ko faaye gba awọn oṣiṣẹ EFCC lati ṣiṣẹ wọn, lojuna ati ri Yahaya gbe lọ.
Awọn kan to n ṣiṣẹ fun gomina to wa nipo nipinlẹ naa bayii, iyẹn Usman Ododo, ni wọn sọ pe wọn fọgbọn fi mọto gomina Ododo gbe Yahaya Bello sa lọ sibi tẹnikankan ko mọ titi di ba a se n sọ yii.