O ma ṣe o! Ijamba ọkọ gbẹmi akẹkọọ Poli l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Dẹrẹba ọkọ kan to ti sa lọ bayii la gbọ pe o ṣokunfa iku to pa akẹkọọ ileewe gbogboniṣe ti ipinlẹ Ọṣun, to wa niluu Iree, lalẹ ọjọ Mọnde ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Akẹkọọ naa, Ọlanrewaju Ọlatọna, la gbọ pe o ṣẹṣẹ pari ipele keji akọkọ ninu ẹkọ rẹ, iyẹn OND 2, to si ti n mura lati lọ fun ikọṣẹmọṣe (IT) ọlọdun kan rẹ.

ALAROYE gbọ pe onimọto kan to gba ọna ti ko yẹ ko gba lo fori sọ ọkada to gbe Ọlanrewaju loju ọna Ikirun si Oṣogbo, lalẹ ọjọ iṣẹlẹ yii.

Bo ṣi ṣe kọ lu ọkada yii lagbara debii pe oju-ẹsẹ ni akẹkọọ yii, ẹni to jẹ akọwe-owo fun awọn akẹkọọ ẹka imọ iroyin, Mass Communication Department, ni Poli Iree jade laye.

Bi dẹrẹba ọkọ ọhun ṣe ri nnkan to ṣẹlẹ lo ti na papa bora pẹlu ibẹru ohun ti awọn to wa lagbegbe naa le ṣe fun un.

Oniruuru ọrọ ibanikẹdun lawọn akẹgbẹ Ọlanrewaju ti n kọ sori ẹrọ ayelujara latigba tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, gbogbo wọn si jẹrii pe ẹni to maa n ko eeyan jọ lọmọkunrin naa.

Alukoro funleeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii ti bẹrẹ lati mu dẹrẹba ọkọ naa.

Leave a Reply