Adewale Adeoye
Alubami, aludaku ati alubajẹ, ni ṣọja kan ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ tabi bareki to ti wa, lu ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ to n fọwọ ofin mu awọn araalu to n ṣe idọti layiika nipinlẹ Eko, ‘Lagos State Environmental Sanitation Corps’ eyi tawọn araalu mọ si KAI, lagbegbe Yaba.
Ṣe lọrọ di rannto l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lagbegbe Yaba, lasiko ti ṣọja naa fẹsun awuruju kan oṣiṣẹ KAI ọhun. Kawọn oṣiṣẹ ajọ ọhun yooku si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ṣọja ọhun ti doju ija kọ ọkunrin naa, o lu u bajẹ debii pe ileewosan ijọba kan to wa lagbegbe naa lo laju si. Ṣe lawọn araalu si bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi wọn nitori ti wọn ko mọ nnkan to le tidi ija naa yọ.
Kọmiṣanna ọrọ ayika nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tokunbo Wahab, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, sọ pe oṣiṣẹ ajọ KAI ọhun ti ṣọja naa fọwọ ba n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba kan to wa lagbegbe Yaba. Bakan naa lo gboṣuba fun bi Ọgagun T Lagbaja, to jẹ ọga ṣọja patapata nilẹ wa ṣe tete pana ọrọ naa, ti ko si dija igboro laarin awọn oṣiṣẹ ijọba mejeeji.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘’Ọpẹ pataki lọwọ Ọgagun T Lagbaja, iyẹn ọga agba patapata fun ileesẹ ologun orileede yii, fun bo ṣe tete wa wọrọkọ fi ṣada lori ija kan to waye laarin oṣiṣẹ ajọ KAI atawọn ṣọja lagbegbe Yaba, nipinlẹ Eko laipẹ yii. Bakan naa la dupẹ lọwọ Ọgagun T.E Ọgbọnyọmi fun ipa pataki toun naa ko lori ọrọ ọhun, igbesẹ wọn fi han gbangba pe wọn ko nifẹẹ si iyanjẹ tabi fifọwọ ọla gba ni loju laarin ilu.
‘’A fi n da awọn araalu loju pe ko sohun tẹnikan le ṣe lati ma ṣe jẹ ki ajọ KAI ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ laarin ilu. Awọn oṣiṣẹ ajọ naa ko ṣẹ ṣọja naa rara, wọn kan mọ-ọn-mọ fẹẹ fọwọ agbara mu awọn ẹniẹlẹni ni, ṣugbọn gbogbo nnkan ti pada bọ sipo bayii, awọn ọga wọn gbogbo ti ba wọn wi.