Aderounmu Kazeem
Ṣọun ilu Ogbomọṣọ, Ọba Jimoh Oyewunmi Ajagungbade ti sọ pe oun ko kọ lẹta kankan lati fi kọ owo ti Gomina Ṣeyi Makinde loun fẹẹ na lori atunṣe aafin tawọn eeyan kan fi ibinu bajẹ lasiko iwọde.
Ninu ọrọ ti Kabiyesi ba amugbalẹgbẹẹ gomina, Ọgbeni Taiwo Adisa, sọ lo ti sọ pe oun ko kọ lẹta kankan, ati pe ti wọn ba ri iru ẹ, wọn ko gbọdọ ka a kun, ki i ṣe inu aafin niru ẹ ti jade sita.
O fi kun un pe gbogbo ipa daadaa ti Gomina Ṣeyi Makinde ba fẹ sa lori atunkọ aafin tawọn eeyan kan bajẹ lasiko iwọde loun fọwọ si.
Kabiyesi sọ pe lẹta tawọn eeyan kan n gbe kiri, ti wọn fi sọ pe oun ti da owo iranwọ ti Ṣeyi Makinde fẹẹ ṣe lori atunṣe aafin pada, ko sootọ nibẹ rara, awọn kan ni wọn tọwọ bọ iwe ọhun ki i ṣe oun loun buwọ lu u.
Ohun ti wọn lo wa ninu lẹta ọhun ni pe Ọba Ajagungbade ti sọ pe ki Gomina Makinde ma ṣe iyọnu lori ọgọrun-un miliọnu naira to loun fẹẹ fi tun aafin kọ foun. Wọn ni Ṣọun sọ pe owo naa ti pọju, ati pe awọn ọmọ Ogbomọṣọ kan ti gba lati gbe inawo ọhun, miliọnu mẹwaa naira pere loun yoo mu ninu ẹ, ko lọọ na aadọrun-un miliọnu naira yooku lori ipese iṣẹ fawọn ọdọ nipinlẹ Ọyọ.
Ṣugbọn Ṣọun Ogbomọṣọ ti sọ pe, oun ko kọ lẹta ọhun rara, iṣẹ awọn eeyan kan ni.