Wọn kọlu Shoprite ni Suurulere, Sangotẹdo, ọpọ ẹru ni wọn n ko lọ

Aderounmu Kazeem

Wahala mi-in tun n ṣẹlẹ bayii ni agbegbe Suurulere, l’Ekoo nigba tawọn janduku kan tun kọlu ile itaja Shoprite ti wọn si n ko wọn lẹru lọ.

Bi a ti ṣe n ko iroyin yii jọ, wọn ni niṣe lawọn ọdọ kan yabo ile itaja ọhun, ti wọn si n ko gbogbo ohun ti ọwọ wọn ba ti ba.

Yatọ si ile itaja Shoprite ti wọn kọlu yii ni Suurulere, bakan naa ni eyi to wa ni Sangotẹdo ni Lekki naa faragba a.

ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn ̀eeyan n ri oriṣiiriṣi ẹru ti wọn ji ko nibẹ lọwọ wọn lagbegbe Ajah atawọn ibomi-in laduugbo naa.

Leave a Reply