Faith Adebọla, Eko
Ilu-mọ-ọn-ka agba ọjẹ onkọwe ilẹ wa nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti tun gba ijọba Muhammadu Buhari to wa lori aleefa bayii nimọran, o ni nibi tọrọ iṣoro aisi aabo de lorileede yii, o ti to asiko fun ijọba apapọ lati kegbajare sawọn to le ran an lọwọ, ki wọn yee dibọn bii ẹni pe apa wọn ka ọrọ to n fojoojumọ fẹju kẹkẹ yii.
Atẹjade kan ti ọkunrin naa buwọ lu funra ẹ, to fi lede lọjọ Abamẹta, Satide yii, lo pe akọle rẹ ni “Fifẹmi awọn ọdọ wa ṣofo lai lopin”, ninu atẹjade naa ni Ṣoyinka ti sọrọ ọhun.
Ṣoyinka ni oju ogun gidi ni Naijiria wa lọwọ yii, ṣugbọn niṣe lawọn kan n ṣe bii ẹni pe inira irọbi lasan ni ohun to n ṣelẹ yii, bii ẹni pe lẹyin inira ranpẹ yii, ayọ maa too tẹle e, bẹẹ itanjẹ lasan ni, ọrọ o ri bẹẹ rara.
Ọjọgbọn naa ni ẹru to n ba oun bayii ni pe afaimọ lọrọ Naijiria ko fi ni i da bii ohun to waye lorileede Russia, nigba tawọn ọmọ ogun Chechen ti wọn lawọn fẹẹ yapa kuro lorileede naa, awọn fẹẹ da orileede olominira Cherchya silẹ, eyi to mu ki wọn fipa kọ lu ileewe ijọba Beslan lọdun 2001, wọn ko awọn ọmọleewe bii ẹgbẹrun kan sigbekun, ti wọn si pa bii okoolelọọọdunrun danu lara awọn ọmọde naa.
O ni “Pẹlu bo ti ṣe han pe alaaarẹ ati alailagbara lawọn to n ṣejọba yii, ko sohun to yẹ wọn ju ki wọn ko itiju ta, ki wọn yee dibọn, ki wọn si wa iranlọwọ sibomi-in, ṣugbọn aja to ba maa sọnu ki i gbọ fere ọlọdẹ.
“Bi Alaaji Atiku Abubakar ṣe sọ ọ lo ri, ọgbẹ ọkan ni ohun to n ṣẹlẹ bayii jẹ fawọn eeyan. Ṣugbọn o ju ọgbẹ ọkan lọ paapaa, niṣe niṣoro aisi aabo yii fa oro nla sọkan ọpọ miliọnu ọmọ Naijiria, ko sẹni tọrọ yii o su, o ti tan wa ni suuru patapata.
“Ẹ ranti awọn iṣẹlẹ jiji awọn ọmọleewe gbe to ti waye kọja nileewe Chibok, nipinlẹ Borno, ati ileewe Dapchi, nipinlẹ Yobe, ọpọ iru ẹ lo si ṣẹlẹ ti wọn o royin ẹ.
“Ohun to kan lati ṣe bayii lo yẹ ka maa sọ, ka si tete ṣe e kiakia ni. Ojoojumọ la n sa fun ohun ti ko ṣee yẹ silẹ, bẹẹ si ni nnkan naa n le wa kiri, o ti n kan geeti mọ wa lori bayii. Oju ogun lorileede yii wa, ojoojumọ lẹyẹ Igun ati Koowee pọṣẹṣẹ lori Naijiria, ọkan wọn balẹ bi wọn ṣe n fo bagẹbagẹ kiri.
Arun Korona lo da ogun lọwọ kọ fungba diẹ, ṣugbọn ohun to ju Korona lọ la n ba yi lọwọ yii. Ẹ jẹ ka pariwo, ka lọgun, boya ijọba yii leti ti wọn fi n gbọ ọrọ: Ẹ wa iranlọwọ lọ o, ẹ kegbare sita o. Ẹ yee fẹmi awọn eeyan ta tẹtẹ, Awọn ọdọ to jẹ awọn lọjọ ọla wa, ẹ yee fi wọn ṣetutu lojubọ orileede to ti fẹẹ wo tan yii o.”
Bẹẹ ni Ṣoyinka pari atẹjade ikilọ ọhun.