Gomina Sanwo-Olu sọ Iya Awẹro di lanlọọdu l’Ekoo, o fun un ni fulaati kan

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Bi wọn ba n sọ pe ilẹ aanu Oluwa ki i ṣu, ẹni kan to maa jẹrii si owe yii lasiko yii ni agba-ọjẹ oṣere-binrin onitiata ilẹ wa nni, Abilekọ Lanre Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Iya Awẹro, latari bi Gomina Sanwo-Olu ṣe fi ile fulaati oni-yara mẹta kan ta a lọrẹ.

Akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gboyega Akosile, lo ju iroyin ayọ naa sori afẹfẹ latori atẹ ayelujara (tuita) rẹ lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee yii, pe “Gomina Babajide Sanwo-Olu ti fa ile alakọọgbe fulaati oniyara-mẹta kan le Abilekọ Lanre Hassan lọwọ lati mọ riri ipa ribiribi ti agba oṣere naa ti ko nidii iṣẹ sinima.

“Oni ni gomina fa kọkọrọ ile naa le Iya Awero lọwọ.

“Bakan naa ni Gomina Sanwo-Olu tun yi orukọ awọn ile akọgbe tijọba ko siluu Igbogbo, lagbegbe Ikorodu pada. LagosHoms ni wọn n pe ile naa tẹlẹ, ṣugbọn Ẹsiteeti Ọmọọba Abiọdun Ogunlẹyẹ ni yoo maa jẹ bayii.”

Gomina Sanwo-Olu sọ nigba to n fun Iya Awero ni kọkọrọ ile rẹ tuntun naa pe o daa lati maa mọyi awọn eeyan ti wọn ti ṣe bẹbẹ nigba aye wọn, nigba ti wọn ṣi wa laaye, ki i ṣe ti wọn ba ti ku. O ni ọkan lara awọn irawọ oṣere tiata ilẹ wa ti wọn ti lo ohun to to ọgbọn ọdun si ogoji ọdun ni mama yii, a si gbọdọ gbe iru wọn larugẹ. “Mo ki yin kuu oriire ma, Ẹ ṣeun, ẹ kuuṣẹ o,” bẹẹ ni gomina ki mama agbalagba yii.

Iya Awero naa ko le pa idunnu rẹ mọra. O fesi pe: “Mi o tiẹ mo ohun ti n ba sọ, mi o mọ ohun ti n ba wi rara. Inu mi dun gidi lọjọ oni. Ẹ ṣeun ṣeun o, gomina wa. Allah aa maa bukun fun yin o. Bakan naa, mo dupẹ lọwọ Igbakeji yin, ẹ ṣeun mi lọpọlọpọ, mo dupẹ, mo tọpẹ da. Bi eeyan ba kọ ile fun ẹda ẹgbẹ ẹ, ko sigba tiru onitọhun maa ji ti ko ni i kọkọ dupẹ fun ẹni to ṣe oore nla bẹẹ fun un. Ọlọrun aa maa bukun fun yin, aa si maa ran yin lọwọ, aa ti yin lẹyin o. Ọlọrun aa jẹ ki alaafia jọba nilẹ wa, aa ba wa yanju awọn iṣorọ wa, aa si mu orileede wa goke agba titi de ilẹ ileri o.

“Lẹẹkan si, mo dupẹ lọwọ gbogbo eeyan fun ẹbun nla yii, ọpẹ oloore, a-du-i-du-tan ni o.”

Bayii ni Iya Awero ṣe fi idunnu rẹ han, o dupẹ gidi, o si gba ijo nibi ayẹyẹ naa, tori oun naa ti di ọkan lara awọn oṣẹre-binrin ti wọn jẹ lanlọọdu nilẹ wa bayii.

Leave a Reply