Oyetọla yan ọmọ Bisi Akande ni kọmiṣanna, o tun fiyawo rẹ ṣe oluranlọwọ lọfiisi ọkọ ẹ

Florence Babaṣọla

Awuyewuye ti bẹrẹ bayii laarin awọn lameetọ ilu ninu iṣejọba ipinlẹ Ọṣun nigba ti aṣiri tu pe ijọba yan iyawo kọmisanna fun eto-idajọ, Ọnarebu Fẹmi Akande, gẹgẹ bii oluranlọwọ pataki nileeṣẹ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu lẹta igbanisiṣẹ ti wọn fun iyawo kọmiṣanna naa, Arabinrin Akande Yeṣide Oyinkansọla, ijọba yan an lọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun 2020, gẹgẹ bii oluranlọwọ (Personal Assistant) si ọkọ rẹ.

Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Oluwọle Oyebamiji, lo fọwọ si iwe igbanisiṣẹ naa, wọn si sọ pe igbanisiṣẹ rẹ bẹrẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2019.

O pẹ ki aṣiri ọrọ naa too tu sita, o si jẹ iyalẹnu fun awọn araalu nigba ti wọn gbọ pe ijọba le ṣe iru nnkan bẹẹ fun kọmiṣanna naa, ẹni to jẹ ọmọ bibi gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Oloye Adebisi Akande.

Gbogbo igbesẹ ti awọn oniroyin gbe lati gbọ tẹnu kọmiṣanna ti ọrọ kan ni ko so eso rere, ko gbe ipe rẹ, bẹẹ ni ko fesi si atẹjiṣẹ ti wọn fi ranṣẹ si i.

Bakan naa ni a ko rẹni fesi lori rẹ ninu Kọmiṣanna feto iroyin, Funkẹ Ẹgbẹmọde ati Akọwe iroyin fun gomina, Ismail Omipidan.

Leave a Reply