Ọbasa ṣatilẹyin fawọn gomina agbegbe Guusu lori bi wọn ṣe fofin de fifi maaluu jẹko

Faith Adebọla, Eko

Olori awọn aṣofin ipinlẹ Eko, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, ti sọ pe gbagbaagba loun wa lẹyin awọn gomina ipinlẹ mẹtadinlogun Guusu ilẹ wa lori ipinnu ti wọn ṣe laipẹ yii lati fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba lawọn ipinlẹ wọn, o ni igbesẹ to maa ṣe awọn araalu lanfaani lawọn gomina ọhun gbe.

Ọbasa sọ lori ikanni ayelujara rẹ pe ipo ti ọrọ aabo to mẹhẹ lorileede yii wa ti de gongo, o si n ṣẹru baayan, latari bi iṣẹlẹ ijinigbe, ifẹmiṣofo ati idigunjale ṣe waa di iṣẹlẹ ojoojumọ, ti kinni ọhun ko si dawọ duro.

Ọbasa ni ilu Eko naa ti n fara gba ninu iṣoro aabo to dẹnu kọlẹ ọhun, tori laipẹ yii lawọn gbọ pe iṣẹlẹ ijinigbe waye lagbegbe Ikẹja, loju ọna Lẹkki si Ẹpẹ, ati lagbegbe Ikorodu, bẹẹ si ni wahala awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ko yee ṣẹlẹ.

Aṣofin naa sọ pe: “Mo gboṣuba fawọn gomina Guusu yii, ipinnu ti wọn ṣe lati fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba, ati awọn mi-in ti wọn ka jade ninu atẹjade wọn lẹyin ipade to waye l’Asaba, nipinlẹ Delta, lati koju iṣoro aabo to mẹhẹ fihan pe akin loju ogun ni wọn, ati pe wọn nifẹẹ araalu ti wọn n ṣakoso le lori dọkan. Inu mi dun si bawọn gomina naa ṣe wa niṣọkan, ti wọn si fi igbanu kan ṣoṣo ṣ’ọja lori ọrọ yii, nnkan to daa gidi ni.

Awọn gomina yii fihan pe aṣoju to ṣee fọkan tẹ lawọn, wọn si ti fi apẹẹrẹ rere lelẹ fun awọn to ku. Ọrọ aabo lorileede yii ti doju ẹ, inu ibẹru lawọn araalu wa, niṣe niṣoro naa si n fẹju kankan si i.

Ojulowo lawọn nnkan tawọn gomina yii sọ pe awọn fẹ, ero wọn si ba ti araalu mu pẹlu.” Bẹẹ l’Ọbasa sọ.

Leave a Reply