Nitori awọn ajinigbe, ẹṣọ Amọtẹkun fẹẹ maa ṣọ awọn aala ipinlẹ Yoruba

Lati mu ki aabo nipọn si i lawọn ipinlẹ Yoruba, ikọ alaabo Amọtẹkun ti fẹnu ko lati maa ṣọ awọn aala awọn ilu ilẹ Yoruba kaakiri.

Alaga awọn olori ogun Amọtẹkun kaakiri ipinlẹ Yoruba, Oloye Adetunji Adeyẹye, lo sọ eyi di mimọ leyin ipade ti wọn ṣe niluu Akurẹ, nibi ti wọn ti fohun ṣọkan pe ohun to dara ni bi ikọ Amọtẹkun ba tun n ṣọ awọn aala ipinlẹ kọọkan, yatọ si pe wọn wa nilẹ Yoruba lasan.

Oloye Adeyẹye ṣalaye pe igbesẹ yii yoo jẹ ko ṣee ṣe lati tete maa ri awọn ọdaran to ba daran niluu kan ti wọn waa sapamọ siluu to sun mọ ọn tabi ti wọn jọ paala pọ.

Bii keeyan daran l’Ondo, ko lọọ fara pamọ s’Ekiti, kia lọwọ yoo to o nigba ti ikọ to n ṣọ aala ilu mejeeji ba ti wa nibuba.

Alaga awọn olori ogun yii tẹsiwaju pe bawọn Fulani darandaran ṣe n fẹran jẹko kaakiri tẹlẹ ti dinku niluu Akurẹ. O ni darandaran to ba ṣe bẹẹ lasiko yii maa n sare fowo itanran bẹ agbẹ ni. Yatọ si ti tẹlẹ to jẹ niṣe ni wọn yoo jẹ gaba le agbẹ lọri, to jẹ awọn agbẹ ko lẹnu ọrọ, afi ki wọn ka a sara bi wọn ko ba fẹẹ jiya lọwọ ẹni to fẹran jẹ wọn loko.

Yatọ si tawọn darandaran yii, Adeyẹye sọ pe awọn ajinigbe paapaa wa ninu idi tawọn fi fẹẹ bẹrẹ igbesẹ tuntun fawọn Amọtẹkun yii.

O lawọn ṣakiyesi pe awọn oju ọna marosẹ lawọn ajinigbe atawọn adigunjale ti maa n ṣọṣẹ ju, paapaa apa ibi ti ọna ko ba ti daa, ti awọn awakọ si ni lati rọra rin tabi ki wọn din ere ti wọn n ba bọ ku.

Gbogbo eyi lo ni o fa a ti Amọtẹkun fi pe ipade lati gbe awọn igbesẹ tuntun yii, bẹẹ lo pe fun ijiya to le gan-an ti ko ni i ni owo itanran ninu rara fawọn ẹni tọwọ ba tẹ pe wọn n jiiyan gbe.

Nipa ofin ma fẹran jẹko ni gbangba, ọkunrin yii ni iṣẹ Amọtẹkun ni lati ri i pe ofin naa fẹsẹ mulẹ gidi lawọn ipinlẹ, ohun tawọn si n ṣe naa niyẹn.

 

 

Leave a Reply