Oluwatosin atawọn ẹgbẹ ẹ ja tirela to kun fun simẹnti gba, wọn ṣa dẹrẹba ladaa yannayanna

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Awọn afurasi adigunjale meje ni wọn n kawọ pọnyin rojọ lọwọ n’ile-ẹjọ Majisireeti kin-in-ni to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.

Awọn afurasi ọhun, Igbasan Oluwatosin, Aur Felix, Sunday Victor, Mọmọdu Sọdiq, Ogbonnaya Gabriel, Isaac Ukpeh ati ẹnikan ti wọn ṣi n wa ni wọn fẹsun meji kan lasiko ti wọn fara han nile-ẹjọ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Awọn olujẹjọ ọhun ni wọn fẹsun kan pe wọn gbimọ-pọ lati digun jale ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ọdun yii, lagbegbe Ọmọtọṣọ, loju ọna marosẹ Ọrẹ siluu Eko.

Ẹsun keji ti wọn fi kan wọn ni pe wọn fipa ja ọkọ tirela kan ti simẹnti Dangote kun inu rẹ fọfọ gba lọwọ awakọ ti wọn porukọ rẹ ni Kiji Ojo Alabi.

Ọkọ ajagbe ọhun ni ni wọn ni owo rẹ to bii miliọnu mejidinlọgbọn, nigba ti owo simẹnti to wa ninu rẹ jẹ miliọnu mẹta le lẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.

Awọn ẹsun mejeeji yii ni wọn lo ta ko abala kẹfa, ikinni ati ekeji ninu akanṣe iwe ofin Naijiria tọdun 2004.

Niṣe lawọn afurasi janduku ọhun kun awakọ naa bii ewurẹ lasiko ti wọn n gbiyanju ati ja ọkọ gba lọwọ rẹ, lẹyin ti wọn gba ọkọ yii tan ni wọn wa a lọ siluu Okitipupa, nibi ti wọn ti ta gbogbo simẹnti inu rẹ tan patapata ko too di pe ọwọ pada tẹ wọn.

Ninu ẹbẹ Ripẹtọ Akintimẹhin Nelson to jẹ agbefọba, o ni ki adajọ fi aṣẹ si i ki wọn le fi awọn afurasi ọhun pamọ sọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Musa Al-Yanus gba ẹbẹ agbefọba wọle pẹlu bo ṣe pasẹ pe ki wọn ko gbogbo wọn pamọ sinu ọgba ẹwọn titi ti dọjọ igbẹjọ mi-in.

Adajọ ọhun ni kawọn mejeeje si wa latimọle àwọn ọlọpaa titi tawọn ọlọpaa yoo fi pari eto lori fífi ojulowo iwe ẹsun wọn ṣọwọ si ọfiisi ajọ to n gba adajọ n gba adajọ nimọran.

 

Ọjọ keje, osu kẹwaa, ọdun yii, lo ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply