Loootọ ni ara Ọlaiya Igwe ko ya, ṣugbọn ọkunrin naa ko ku o

Aderohunmu Kazeem

Iroyin to gbale gboko lati aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni pe ọkan ninu awọn gbajumọ oṣere ilẹ wa nni, Ẹbun Oloyede ti gbogbo eeyan mọ si Ọlaiya Igwe, ti jade laye.

Ọrọ naa kọkọ da ijaya nla silẹ nitori ọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja ni oṣere naa ṣe ọjọọbi, ti gbogbo awọn ololufẹ rẹ atawọn oṣere ẹgbẹ rẹ si n ki i ku oriire. Ko si fi oju han rara pe nnkan kan n ṣe oṣere naa.

Eyi lo mu ki akọroyin ALAROYE fimu finlẹ lati wadii okodoro ọrọ naa. Ninu iwadii ta a ṣe, ọkan ninu awọn oṣere ta a pe to ba wa sọrọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣalaye pe loootọ ni oṣere ọmọ bibi ilu Abẹokuta naa wa ni idubulẹ aisan. O ni iṣẹ abẹ to ni i ṣe pẹlu kindinrin lo lọọ ṣe ni ileewosan ẹkọṣẹ Yunifasiti Ibadan (UCH), nipinlẹ Ọyọ. Wọn ni okuta wa ninu kindinrin rẹ ni wọn tori ẹ ṣiṣẹ abẹ fun un gẹgẹ ba a ṣe gbọ, o ṣi wa nibẹ to n gba itọju lọwọ.

Bakan naa ni agba oṣere nni, Awofẹ Afọlayan, fidi ọrọ naa mulẹ fun wa pe loootọ loṣere naa ṣiṣẹ abẹ ni ọsibitu UCH, n’Ibadan, loootọ, ara rẹ si ti n mokun diẹdiẹ. O ni oun pe iyawo Ẹbun Oloyede nigba toun gbọ nipa ariwo ti wọn n pa kiri nipa agba oṣere naa lati fidi rẹ mulẹ, obinrin naa si sọ pe loootọ ni o rẹ oṣere naa diẹ, to si ti n gbadundaa daa.

Ṣugbọn ki i ṣe pe ọkunrin naa ti ku bi awọn eeyan ṣe n gbe e kiri.

A gbọ pe ọpọlọpọ awọn oṣere ti wọn gbọ nipa aiyaara Ẹbun Oloyede ni wọn n gbadura kikan kikan pe ki Ọlọrun tete yọnda alaafia fun un.

Leave a Reply