Danjuma to lu iyawo ẹgbọn ẹ pa ti wa lahaamọ

Ko si bi ọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Danjuma Haruna yoo ti ṣe e ti ko ni i kawọ pọnyin rojọ lori iku iyawo ẹgbọn rẹ, nitori oun lo lu obinrin naa, Zuwaira Bala, tiyẹn fi jade laye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ yii.

Ohun to ṣẹlẹ yii ti sọ Danjuma dẹni ti wọn fi pamọ, ahamọ ọlọpaa lo wa nipinlẹ Jigawa to ti daran ipaniyan.

ASP Lawan Shiusu Adam ti i ṣe Alukoro ọlọpaa Jigawa, ṣalaye pe agboole awọn Danjuma to wa ni abule Gamatan, niṣẹlẹ yii ti waye, nijọba ibilẹ Migawa.

Ọga ọlọpaa naa tẹsiwaju pe ọrọ kan lo ṣe bii ọrọ laarin Danjuma, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ati iyawo ẹgbọn ẹ, Zuwaira, toun naa jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.

Ọrọ naa di wahala to bẹẹ to fi di pe wọn n wọya ija, ti Danjuma ko si wo ti pe obinrin loun ba ja gidigbo, ko si tun ro ti pe iyawo ẹgbọn oun ni Zuwaira i ṣe.

Nibi ti wọn ti n ja ija ọhun lọ ni Danjuma ti gbẹsẹ soke bawọn ọlọpaa ṣe wi, o si sọ ipa to lagbara si ikun iyawo ẹgbọn ẹ, n lobinrin naa ba ṣubu lulẹ, o daku lọ rangbọndan.

Awọn eeyan to ti n la wọn tẹlẹ ti wọn ko gbọ naa lo sare gbe Zuwaira lọ sileewosan, ṣugbọn ohun to balẹ si i nikun naa ti de ibi ẹmi ẹ, ko si pẹ lẹyin to de ileewosan Jẹnẹra Jahun ti wọn gbe e lọ to fi dagbere faye.

Aburo ọkọ ẹ to da ẹmi ẹ legbodo gbiyanju lati sa lọ lẹyin toju rẹ walẹ tan, o tilẹ ti kuro lagbegbe to ti daran, ibi kan ti wọn n pe ni Hadejia, ni wọn ti ri i mu gẹgẹ bii alaye Alukoro.

Latigba tọwọ si ti tẹ ẹ naa lo ti wa ni gbaga, o ṣee ṣe ko foju ba kootu lọsẹ yii lati ṣalaye bi ẹsẹ rẹ ṣe paayan lọsan-an gangan.

Leave a Reply