Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ọmọ Yoruba ati Ibo ti wọn wa niluu oyinbo ti n gbaradi bayii lati bẹrẹ iwọde ni Washington, bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ yii. Olu ile Ajọ Agbaye (United Nation) ni wọn yoo ti bẹrẹ iwọde ọhun, lati kede ohun ti oju awọn Yoruba ati Ibo n ri ni Naijiria, ati idi ti wọn fi n beere fun orilẹ-ede kaluku wọn.
Iwọde yii ni akọkọ iru ẹ ti yoo jẹ ajọṣepọ laarin ẹya meji. Ṣe tẹlẹ, kaluku n da ẹkun ijangbara rẹ sun ni. Bi Yoruba ṣe n kigbe ‘Oduduwa Nation’ ni awọn Ibo naa n sọ pe Biafra lawọn fẹ, awọn ko fẹ Naijiria mọ.
Bi wọn ba ti fi iwọde alaṣepọ lelẹ tan lolu ile ẹgbẹ UN, iwọde taara ti gbogbo aye yoo gbọ yoo waye l’Ọjọbọ, Ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, yoo tun waye lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ati ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọdun 2021.
Yatọ si ile ẹgbẹ Ajọ Agbaye, awọn ibomi-in ti wọn yoo ti kora jọ fun iwọde naa ni Ẹmbasi ilẹ Gẹẹsi, eyi to wa ni 3100, Massachusetts Avenue, ni ẹkun Ariwa Washington.
Ibomi-in ti awọn ajijagbara ọmọ Yoruba ati Ibo naa yoo tun ti kora jọ ni White House ati Capitol Hill, nibi ti ileegbimọ orilẹ-ede United State wa.
Ki ọjọ iwọde yii too pe, awọn oluwọde ti wọn jẹ Yoruba, ti wọn n beere Ilẹ Olominira Yoruba, yoo kọkọ ṣewọde kan, iyẹn lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ajijagbara naa, Oluwọle Adigun, ṣe sọ fun ẹka iroyin Irohin oodua, o ni awọn fẹ kawọn ajọ agbaye kaakiri mọ iya to n jẹ awọn eeyan to n beere fun iyapa kuro lara Naijiria ni.
O ni eyi ni akọkọ iwọde ti yoo jẹ alajọṣepọ pẹlu ẹya mi-in to yatọ si Yoruba, ṣugbọn awọn ṣetan lati fọwọsowọpọ, ki ominira tawọn n ja fun le ṣee ṣe.
Awọn to gbe iwọde yii kalẹ fẹ ko fẹnu sọ ipade Ajọ Agbaye ti wọn yoo ṣe loṣu kẹsan-an ni, kawọn ara aye yooku le mọ ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria ni wọn ṣe mọ-ọn-mọ gbe e sasiko ti wọn gbe e si yii.
Bawọn Yoruba ba da ọkan ṣe ni ọjọ kẹrinla ati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, alajọṣepọ pẹlu awọn Ibo yoo si tun waye lọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọjọ kin-in-ni, ati ọjọ keji, oṣu kẹwaa.
Ko sohun to tun fa iwọde ti wọn n gbero rẹ niluu oyinbo yii ju pe awọn eeyan naa fẹẹ fẹjọ Aarẹ Muhammadu Buhari sun Ajọ Agbaye, nitori ọkunrin naa ti sọ pe awọn ti ko ni oju inu ni wọn n beere ipinya ni Naijiria, ijọba oun ko nigbagbọ ninu ipinya, oun yoo si ri i pe Naijiria duro lọkan ṣoṣo ni.
Bakan naa ni Alaaji Lai Muhammed to jẹ minisita eto iroyin ati aṣa naa sọ pe awọn to n fẹ ki Naijiria pin yii ko ni idahun kan si iṣoro to n koju Naijiria, ipinya ti wọn ro pe o le ṣe e yii ko si le bimọ ire.
Ṣugbon awọn ajijagbara lawọn ko ni i gba, iyẹn naa lo si fa a ti wọn tun fi fẹẹ bẹrẹ ẹ nilẹ alawọ funfun.