Faith Adebọla, Eko
Ọtafa-soke-yido-bori ẹda kan bayii ni Fẹmi Abdulmalik Salau, ṣugbọn aṣiri afurasi ọdaran naa tu pe oun lo wa nidii fifi ẹrọ ayelujara lu awọn banki ilẹ wa kan ni jibiti, to si n gbọna ẹburu wọ obitibiti owo jade ninu akaunti wọn.
Ẹka Special Fraud Unit, SPU, to n tọpinpin iwa jibiti de gongo nileeṣẹ ọlọpaa, lo ṣafihan Fẹmi l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, wọn ni oun ni amookun-ṣika to fi ẹrọ kọmputa ati foonu rẹ wọ owo lọ ninu asunwọn awọn banki, aropọ owo to si ti lu jibiti rẹ din diẹ ni biliọnu meji naira (N1.87 billion).
Nigba to n ṣalaye ọrọ naa lọfiisi wọn to wa n’Ikoyi, Agbẹnusọ SFU, DSP Eyitayọ Johnson, sọ pe ori okun alatagba tawọn eleebo n pe ni safa (server) to jẹ tileeṣẹ Flex-Cube Universal Banking System (FCUBS) ni Fẹmi gba lọ latori intanẹẹti ninu kọrọ yara rẹ, safa naa lo gba de inu akaunti awọn banki nla mẹta ilẹ wa kan ti wọn forukọ bo laṣiiri, lo ba bẹrẹ si i ‘wọke’ owo wọn jade, o si n kọ ayederu figọ sibẹ, kawọn banki naa ma baa tete fura.
Sibẹ, awọn oṣiṣẹ ọkan lara awọn banki ti wọn fara kaaṣa naa lo fura pe nnkan kan ti ṣẹlẹ, ni wọn ba kan sileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn ba awọn da si i, nileeṣẹ ọlọpaa fi fa ọrọ le ẹka SFU wọn lọwọ.
Lẹyin ọpọ iwadii ijinlẹ, imọ ẹrọ ati iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, awo ya mọ Fẹmi Salau lori, oun ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan tawọn ọlọpaa ṣi n wa lọwọ ni wọn huwa abeṣe ọhun.
Johnson ni nigba tawọn mu afurasi ọdaran naa, o jẹwọ pe loootọ loun atawọn ọrẹ oun kan jale owo ti wọn n sọ, wọn lo jẹwọ pe nnkan bii miliọnu okoolenirinwo o din meji naira ninu owo awọn onibaara banki ti wọn fi n ranṣẹ lati banki kan si omi-in lawọn dari gba ibomi-in, ni wọn ba n fi owo olowo ṣara rindin.
Lara ẹsibiiti ti wọn ka mọ Fẹmi lọwọ ni ẹrọ kọmputa agbeletan (Apple laptop) kan, foonu Apple kan, wọn si ti fi pampẹ ofin gbe awọn oniṣowo paṣipaarọ owo, Bereau de Exchange, wọn lawọn ni wọn n ba Fẹmi paarọ owo to ‘wọke’ ẹ, wọn si maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ laipẹ.