Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja 11, ti koro oju si bi awọn kan ṣe maa n fi ẹnu ṣaata ẹsin Iṣẹṣe, ti wọn maa n foju ẹlẹṣẹ wo awọn ẹlẹsin naa.

Nibi ayẹyẹ ọdun iṣẹṣe ti ọdun yii, eleyii ti awọn ẹlẹsin naa, labẹ Traditional Worshipers Association of State of Osun (TRWASO), ṣagbekalẹ rẹ niluu Oṣogbo lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Ọọni ti sọ pẹ iyi ati ẹyẹ to yẹ fun awọn ẹsin to ku lorileede yii tọ si ẹsin abalaye pẹlu.

Ọọni, ẹni ti Agbolu ti Agbaje Ifẹ, Ọba Adekunle Adebọwale, ṣoju fun ṣalaye pe gbogbo eeyan lo lanfaani lati sin ẹsin wọn lọna to ba igbagbọ wọn mu lai si idiwọ lati ọdọ ẹnikẹni.

Ọba Adeyẹye waa gboṣuba fawọn ọmọ ẹgbẹ TRWASO fun iduroṣinṣin wọn, eleyii ti eso rẹ n farahan lọwọlọwọ, bẹẹ lo gbadura aṣọdunmọdun fun wọn.

Ṣaaju ninu ọrọ ikini ku aabọ rẹ, aarẹ TRWASO, Dokita Oluṣeyi Atanda fi idunnu rẹ han si oniruuru itẹsiwaju to ti n ba ẹgbẹ naa, o ni ipinlẹ Ọṣun ni ipinlẹ akọọkọ ti ẹgbẹ naa yoo ti fi ipilẹ sẹkiteriati wọn, eyi ti wọn ri gba lọwọ ijọba, lelẹ lorileede yii.

Atanda dupẹ lọwọ Gomina Adegboyega Oyetọla fun iṣẹ takuntakun to n ṣe lori idagbasoke ẹsin abalaye, bẹẹ lo dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ fun ifọwọsowọpọ wọn.

Ninu ire Ọsẹ-Otura rẹ, Araba Awo ti ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, dupẹ lọwọ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla fun bo ṣe fi ipilẹ ayajọ ọdun iṣẹṣe lelẹ nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Gomina Oyetọla fun bi ko ṣe yẹ kuro lori ipilẹ naa.

Ẹlẹbuibọn waa rọ gbogbo awọn ẹlẹsinjẹsin lati maa gbe papọ lalaafia, ki anfaani wa fun ẹnikọọkan lati sin ẹsin rẹ lai si wahala latọdọ ẹnikẹni rara.

Bakan naa ni Gomina Oyetọla, ẹni ti Kọmiṣanaa fun ọrọ aṣa atibudo nnkan isẹmbaye, Ọnarebu Simeon Ọbawale Adebisi, ṣoju fun, ṣeleri pe ọrọ igbaye-gbadun gbogbo araalu ni yoo tubọ maa jẹ akọọkọ ninu igbesẹ oun.

Leave a Reply