Ọmọ Yahoo mẹrindinlọgọta bọ sọwọ EFCC l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọmọ to ni iya oun ko ni i sun, oun naa ko ni i foju le oorun lawọn EFCC fọrọ ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹtala, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021, nigba ti wọn wọ otẹẹli ijọba ipinlẹ Ogun, Mitros, to wa n’Ibara, l’Abẹokuta, laago mẹrin idaji kutukutu, ti wọn si ko awọn gende rẹpẹtẹ ti wọn ni ọmọ Yahoo ni wọn.

Ki i ṣe Mitros nikan lawọn ajọ to n ri si jibiti ṣiṣẹ yii wọ, wọn tun lọ si otẹẹli kan ti wọn n pe ni Daktad, ni Quarry Road, ati ọkan ti wọn n pe ni Cecilia, n’Ibara, l’Abẹokuta, kan naa.

Wọn wọ yara awọn alejo to wa lawọn otẹẹli naa, wọn si ko awọn ti wọn ni ọmọ Yahoo ni wọn jade. Nigba ti wọn si pari iṣẹ yii, ko din ni ọmọ Yahoo mẹrindinlọgọta (56) ti wọn ri ko.

Awọn mọto ayọkẹlẹ olowo nla, foonu olowo nla, kọmputa alagbeletan lawọn agbofinro naa gba lọwọ awọn ti wọn mu yii.

Bi wọn ṣe waa pọ to yii tọwọ ba, a gbọ pe awọn kan ṣi ribi sa si lawọn otẹẹli naa, ti ọwọ ko ba wọn lọjọ yii.

Agbẹnusọ EFCC lọfiisi wọn n’Ibadan, Tokunbọ Ọdẹbiyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni mẹrindinlọgọta lawọn eeyan tawọn ko lotẹẹli mẹta l’Abẹokuta, nitori awọn fura si wọn pe Yahoo ni wọn n ṣe jẹun.

Leave a Reply