Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Satide, ọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja, leto idibo lati yan awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP ni tibu-tooro wọọdu gbogbo to wa nijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Ọyọ waye.
Bo tilẹ jẹ pe eto idibo naa lọ wọọrọwọ lagbegbe ọhun, sibẹ o foju han pe ko si iṣọkan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ti kudiẹ-kudiẹ si pada foju han latari bawọn kan ṣe ko ara wọn jọ sẹgbẹẹ kan lati ṣeto idibo tiwọn. Lara ijọba ibilẹ mẹjọ ti akọroyin wa tọpinpin eto naa de ni ijọba ibilẹ Ọlọrunṣogo, Oorelope, Ila-Oorun Ṣaki, ijọba ibilẹ Atisbo, Itẹsiwaju, Irẹpọ, Itẹsiwaju ati Kajọla.
Wamuwamu lẹsẹ awọn agbofinro pe sibi eto ọhun.
Nijọba ibilẹ Ọlọrunṣogo, niluu Igbẹti, meji lawọn ọmọ ẹgbẹ pin si, nibi ti awọn alatilẹyin Gomina Ṣeyi Makinde atawọn ti igun Mulikat Adeọla Akande ti ṣeto wọn nileewe alakọọbẹrẹ NUD keji to wa lagbegbe Oke-lbukun.
Ẹni to jẹ Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ijọba ibilẹ naa, Ọgbẹni Ọladele Saminu, ṣalaye pe iyapa to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ ko ṣẹyin bawọn kan ṣe n ta ko iṣejọba Makinde.
O waa rọ wọn lati bomi suuru mu, lati le jẹ ki ẹgbẹ tẹsiwaju.
Bakan naa lọmọ ṣori nijọba ibilẹ Atisbo ati Itẹsiwaju, bo tilẹ jẹ pe eeyan perete lawọn alatako, sibẹ wọn ṣeto tiwọn. Alaga ijọba ibilẹ Atisbo, iyẹn Ọnarebu Fasasi Adeagbo ati akẹgbẹ rẹ nijọba ibilẹ Itẹsiwaju, Ọnarebu Bọlaji Ojo, ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi ti ko jẹ tuntun ninu ẹgbẹ oṣelu tawọn ọlọpọlọ pipe ba wa, tawọn yoo si yanju rẹ laipẹ bii ọmọọya kan naa.
Ọgbeni Azeez Adeoti, Alaga ẹgbẹ nijọba lbilẹ Oorelope ati akẹgbẹ rẹ nijọba ibile Irẹpọ, Ismail Ọdẹdeji, ṣapejuwe eeto naa gẹgẹ bii aṣeyọri rere, eyi ti yoo mu ẹgbẹ oṣelu PDP gbegba oroke ninu eto idibo ọdun 2023.