Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbogbo awọn ti wọn gbọ nipa iwa ootọ ti ọlọpaa kan, Inspẹkitọ Sheu Saliu, ṣafihan rẹ nipinlẹ Ọṣun ni wọn n gboriyin fun un.
Agbofinro yii la gbọ pe o da ẹgbẹrun lọna igba naira to ri he pada fun obinrin oniṣowo to ni i.
Lati Ṣẹkọna ni wọn ni obinrin oniṣowo epo-pupa ọhun, Bọlarinwa Iyalode, ti gbe ọkada kan to n lọ si Akoda, ko si tete fura pe owo naa ti ja bọ lara rẹ titi ti wọn fi de Akoda.
Bo ṣe sọ kalẹ lori ọkada to ri i pe owo ti ja bọ lo figbe ta, to si bẹrẹ si i wa a bii okinni. Bayii ni wọn tun gbera pada si Ṣẹkọna ti wọn ti n bọ, ti wọn si ṣe kongẹ Inapẹkitọ Saliu.
Lẹyin ti iyẹn beere ohun ti wọn n wa, ti wọn si sọ pe owo ni, o beere ẹri lati le fidi rẹ mulẹ pe obinrin yii lo ni owo ọhun loootọ, obinrin naa si yege gbogbo ibeere naa. Bayii ni ọlọpaa naa gbe owo ọhun fun Arabinrin Bọlarinwa.
Iyalẹnu ni igbesẹ naa jẹ fun gbogbo awọn ti wọn wa nibi iṣẹlẹ naa, wọn ni Saliu ko huwa bii awọn ọlọpaa orileede Naijiria kan.
Bakan naa ni obinrin yii gboṣuba fun kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun fun iwa ọmọluabi to gbin sinu awọn atẹle rẹ, o ni olotitọ eniyan ni Inspẹkitọ Saliu, ati pe Ọlọrun lo o lati ṣaanu oun nitori iṣẹlẹ naa iba doju okoowo oun bolẹ patapata.