Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
“Mo maa pa ara mi danu ni bi kootu ba kọ lati tu igbeyawo emi ati Funmilayọ ka, latigba to ti sọ ara ẹ di anfaani adugbo ni gbogbo ọkunrin ti n ba a sun kiri. Ko si ayọ ninu famili mi mọ tipẹtipẹ, ibanujẹ lo n gba ọkan mi nitori iṣekuṣe tiyawo mi n ṣe kiri. Ẹ tu wa ka ni o, mi o fẹ ẹ mọ.”
Bayii ni baba kan, Amos Akinlolu, ẹni ọdun mẹrinlelọgọta (64) to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba ṣe sọrọ nipa iyawo ẹ, Funmilayọ, to bimọ marun-un fun un.
Kootu kọkọ-kọkọ to n jokoo ni Mapo, n’Ibadan, ni baba naa ti sọrọ yii, koda, ori ikunlẹ lo wa to ti n rawọ ẹbẹ si kootu naa pe afi ki wọn tu ajọṣepọ ọlọdun gbọọrọ naa ka, o ni bi wọn ko ba ṣe bẹẹ, oun yoo pa ara oun ni.
Ṣugbọn Funmilayọ to fẹsun kan sọ fun kootu pe oun ki i ṣe alagbere. O ni lati ọjọ t’ọkọ oun ti n fẹsun agbere ati iṣekuṣe kan oun yii, ko ka ọkunrin kankan mọ oun lori ri, ko si le tọka si ọkunrin kan to ba oun lo pọ ri, o kan wulẹ n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ ko le baa le oun jade nile ni.
Nibi ti ọrọ yii le de, awọn ọmọ wọn maraarun naa sọ pe awọn fọwọ si ipinya laarin baba ati mama awọn. Wọn ni alaafia ko si ninu ile awọn mọ, ko si ma di pe ẹnikan yoo pa ẹnikan ninu iya ati baba awọn, yoo daa ki kootu kuku tu wọn ka ki kaluku maa ba tiẹ lọ.
Aarẹ kootu naa, Abilekọ Imọlẹayọ Akinrodoye, tu igbeyawo naa ka, o ni ki alaafia le wa, ki tọkọ-taya naa tuka.
O ni kawọn ọmọ mẹta ti wọn bi gbẹyin ti ọjọ ori wọn ṣi kere wa lọdọ iya wọn. Bẹẹ ladajọ paṣẹ pe ki Amos san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fun Funmilayọ ko le fi gba ile mi-in ti yoo maa gbe. Bakan naa lo ni bi oṣu ba ti n pari, ki ọkọ to kọ iyawo ẹ silẹ yii maa san ẹgbẹrun mẹwaa naira fun owo ounjẹ ọmọ kọọkan ti yoo maa gbe pẹlu iya wọn.
O rọ wọn lati ma ṣe ba ara wọn fa wahala kankan bi wọn ba pade ara wọn ni titi, niṣe ni ki kaluku maa lọ nilọ ẹ, bi wọn ko ba fẹẹ lufin ijọba.