Iwadii bẹrẹ lori akẹkọọ-gboye fasiti tawọn kan ju oku ẹ sẹgbẹẹ titi lẹyin ti wọn fipa ba a lopọ tan

Faith Adebọla

Awọn amookunṣika ẹda kan ti sọ ala ati ireti ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) kan, Joy Ogochukwu Onoh, dofo, latari bi wọn ṣe da ẹmi rẹ legbodo, ti wọn si ju oku ẹ ṣẹgbẹẹ titi marosẹ, l’Ọjọruu, ọsẹ yii.

Iṣẹlẹ ibanujẹ naa la gbọ pe o waye niluu Makurdi, ipinlẹ Benue.

Ba a ṣe gbọ, lẹta ti wọn maa fi pe oloogbe yii si ibudo ti wọn yoo ti gba idalẹkọọ pẹlu awọn agunbanirọ to fẹẹ ṣiṣẹ sin ilẹ baba wọn ni ọmọbinrin naa n reti, laimọ pe iku ojiji ti lugọ de e ni kọrọ. O ṣẹṣẹ kẹkọọ-gboye ninu imọ eto iroyin (Mass Communication) tan lọdun yii ni Fasiti ipinlẹ Benue to wa niluu Makurdi ni.

Ninu alaye kan ti ọrẹ ẹ, Patience Onuche, ṣe fawọn oniroyin lori iṣẹlẹ naa, o ni oloogbe naa maa n ta awọn ọja keekeekee kan lori atẹ ayelujara, o si lawọn kọsitọma ti wọn maa n ba a raja, ti wọn si maa n pe e lori aago rẹ.

“Joy maa n taja lori ẹrọ ayelujara, o maa n ṣafihan awọn ọja to n ta lori ikanni rẹ, awọn kọsitọma si maa n pe e lati ba a raja. Nigba mi-in, ti wọn ba ti sanwo, oun lo maa n mu ọja lọọ fun wọn, tabi ki wọn waa gba a nibi ti wọn ba jọ fadehun si.

L’Ọjọruu, ẹnikan loun fẹẹ ra suẹta lọwọ ẹ, oun si fẹ ko ba oun mu un wa. Ọdọ mi ni suẹta naa wa, tori mo ti mu un fun ẹnikan tẹlẹ to loun fẹẹ ra a ko too di pe iyẹn o ra a mọ, tori ko ba a tọhun mu daadaa.

‘‘Nnkan bii aago marun-un kọja ogun iṣẹju lo waa gba suẹta naa lọdọ mi, o dagbere fun mi pe oun n lọ si agbegbe North Bank lọọ mu un fun ẹni to ni koun mu un wa. Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ, afẹsọna rẹ pe mi lati beere boya ọdọ mi ni Joy wa, mo ni rara. Ni mo ba pe mama ẹ lori aago, mo gbọ ti iya naa n sunkun pe oun o ri ọmọ oun mọ o, ni mo ba sare ki aṣọ sọrun, mo lọ sile wọn, ile naa ko fi bẹẹ jinna sọdọ wa.

‘‘Nigba ti mo dele wọn, mo tun fi foonu aunti rẹ pe nọmba ẹ, ko wọle, o n sọ pe nọmba naa wa lori ipe kan, o n sọ ‘nọmba bisi.’ Ṣugbọn nigba to di aago mẹwaa alẹ, wọn fi nọmba ọrẹ mi yii pe ti aunti ẹ, ọwọ mi ni foonu aunti ẹ naa wa, ni mo ba gbe e. Joy funra ẹ lo n sọrọ, mo ri i pe nnkan aburu kan ti ṣẹlẹ si i, tori niṣe lo n sọrọ jẹẹjẹ bii ẹni ti ẹmi ti fẹẹ bọ lẹnu ẹ, mo beere pe nibo lo wa, ko fesi, niṣe lo kan sọ fun mi pe ki n fi nọmba akaunti UBA oun ṣọwọ soun lori foonu, mo ni ki lo ṣẹlẹ, o ni oun maa maa ṣalaye fun mi to ba ya, ki n ṣa a fi nọmba naa ṣọwọ na.

Mo tun bi i pe nibo lo wa sẹ, bẹẹ ni ipe naa re bete, ni nọmba ẹ ko ba wọle mọ, mo pe e titi, niṣe lo n sọ pe wọn ti pa foonu ọhun tabi pe netiwọọku ko daa.

Iyalẹnu gba a lo jẹ nigba ti wọn fi fọto oku ẹ ṣọwọ si mi lori ikanni Wasaapu mi. Mo fẹrẹ daku. Awọn eeyan ti wọn n gbe adugbo Federal Housing, lagbegbe North Bank, nibi ti wọn ti ri oku rẹ sọ pe ihooho goloto ni oku naa wa, a ri i pe wọn ti fipa ba a lo pọ ki wọn too pa a, ti wọn si ju oku ẹ sẹgbẹẹ igbo ṣuuru kan to wa ni titi ọhun.”

Iya oloogbe naa, Abilekọ Grace Onoh, sọ fawọn oniroyin pe lati bii ọdun mejila ni ọkọ oun to jẹ baba awọn ọmọ yii ti ku, oloogbe yii ni akọbi, ọmọ mẹta pere naa loun bi, funra ọmọbinrin yii lo si ja fitafita lati ran ara ẹ niwee, tori ko fi bẹẹ si owo lọwọ oun, bukata si wọ oun lọrun latigba tọkọ oun ti ku, pẹlu worobo toun fi n pawọ-da niwaju ile.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue, DSP Catherine Anene, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti gbọ si i, o ni nnkan tawọn kọkọ gbọ ni pe ọmọbinrin naa sọnu, ṣugbọn ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ naa lawọn ri oku ẹ nibi ti wọn ju u si.

O lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti fọn ka gbogbo agbegbe naa lati wadii awọn apamọlẹkunjaye ti wọn da ẹmi ẹ legbodo, awọn si ti gbe oku naa lọọ sọsibitu fun ayẹwo finnifinni.

Leave a Reply