Faith Adebọla
Ile-ẹjọ giga kan ti paṣẹ pe ahamọ ọgba ẹwọn ni ki olukọ ileewe pamari kan, Ọgbẹni Sanusi Makasusi, ti lo iyoku igbesi aye rẹ, ẹwọn gbere ni wọn sọ ọ si, latari ẹsun biba ọmọ ọdun marun-un laṣepọ ti wọn lo jẹbi ẹ.
Ilu Kazaure, nipinlẹ Jigawa, lapa Oke-Ọya ilẹ wa, nidaajọ naa ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Alaye ti agbefọba ṣe ni kootu lori ọrọ naa ni pe ọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun yii, ni ọdaran ọhun huwa buruku naa, lẹyin to dọgbọn mu ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa lọ si kọrọ kan lẹyin ọgba ileewe to ti n ṣe olukọ, to si fipa gbo ọmọ ọlọmọ mọlẹ yankanyankan.
Nigba ti awo ọrọ naa lu, wọn fi pampẹ ofin mu Sanusi lọjọ keji, lẹyin iwadii ni wọn wọ ọ lọọ sile-ẹjọ, nibi ti wọn ti fẹsun ifipabanilopọ, hihuwa aidaa sọmọde ati fifọwọ kan ọmọde lọna aitọ kan an.
Wọn lawọn ẹsun yii ta ko isọri kẹta, iwe ofin iwa ọdaran ati aṣemaṣe tọdun 2014, tipinlẹ Kaduna n lo, ijiya to gbopọn lo si wa fẹni to ba jẹbi ẹṣẹ naa.
Lasiko igbẹjọ, ẹlẹrii marun-un ọtọtọ ni olupẹjọ pe wa, ti wọn jẹrii ta ko olujẹjọ naa.
Adajọ kootu naa, Abilekọ Hassaina Adamu Aliyu, ni ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ oun pọ to, o si tẹwọn, lati fidi ẹ mulẹ pe loootọ lafurasi ọdaran naa huwa idọti ọhun, ki i ṣe pe wọn purọ mọ ọn.
Latari eyi, adajọ ni ọgba ẹwọn ni ile ti Sanusi yoo maa gbe lati asiko yii lọ fun iwa ẹranko to hu yii, ibẹ lo maa wa titi tọlọjọ aa fi de ba a.