Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Olori ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Dokita Bukọla Saraki, ti sọ pe apẹẹrẹ ti han pe laipẹ, awọn eeyan pataki pataki ninu ẹgbẹ oṣelu APC yoo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Saraki sọrọ naa nileeṣẹ Tẹlifiṣan kan ti wọn pe ni Arise lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan to waye. Saraki ni ki eto idibo gbogbogboo ọdun 2023 too de ni awọn eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC yoo ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣugbọn wọn o ni i tete kuro. Lasiko ti ẹpa ko ni i boro mọ ni wọn yoo ya danu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun.
Saraki tẹsiwaju pe awọn n reti awọn eekan ọhun lati inu ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ, o ni ẹni ti ayo oṣelu naa ba ye yoo mọ pe awọn alagbara ki i tete kuro ninu ẹgbẹ ti wọn ba wa lasiko, ṣugbọn ki awọn araalu ṣaa maa woran, nitori wọn n pada bọ laipẹ. O tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP naa ti padanu ọmọ ẹgbẹ rẹ sọwọ ẹgbẹ oṣelu APC, paapaa ju lọ awọn gomina to n ṣejọba lọwọ bii, Ben Ayade Gomina ipinlẹ Cross River, Dave Umahi tipinlẹ Ebonyi, ati Bello Matawalle ti ipinlẹ Zamfara. Bakan naa o ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti setan bayii lati gba agbara kuro lọwọ Aarẹ Muhammed Buhari ati ẹgbẹ oṣelu rẹ APC.