Monisọla Saka
Pasitọ agba ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayọdele, ti ṣekilọ fajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, lati ma ṣe dawọ le eto idibo ọdun 2023, gẹgẹ bi wọn ṣe ti la a kalẹ.
Ninu atẹjade kan ti Oluranlọwọ ẹ lori eto iroyin, Ọshọ Oluwatosin, fi lede, Primate Ayọdele ni ti wọn ba fagidi ṣe eto idibo yii lọjọ ti wọn kede ẹ, o ni eto idibo naa ko ni i waye lawọn apa ibi kan, nitori awọn eeyan kan maa ba a jẹ, eyi yoo si ṣokunfa rogbodiyan nla.
O fi kun un pe ti ajọ INEC ba fẹ keto idibo naa yọri si rere, afi ki wọn sun un siwaju, ki wọn le tubọ ribi gbaradi daadaa.
“Ti ajọ INEC ko ba sun eto idibo gbogbogboo siwaju, ko ni i waye lawọn apa ibi kan, eleyii yoo si ṣokunfa kawọn eto idibo apa ibi kan ma niyanju. Awọn eeyan kan ni wọn yoo dabaru eto idibo naa lawọn apa ibẹ”.
Bakan naa ni oluṣọaguntan yii fi kun un pe, ọna kan ṣoṣo ti wọn le fi wa ojutuu si iṣoro Naijiria ni lati ṣe atunto awọn nnkan kan, dipo eto idibo ti wọn n palẹmọ fun. O ni ti wọn o ba ṣe atunto ati atunṣe to yẹ laipẹ yii, orilẹ-ede yii le doju ru patapata. Ati pe tawọn ijọba ba kọ lati ṣatunṣe to yẹ nilẹ yii ni kiakia, awọn eeyan maa ṣe ifẹhonu-han to lagbara.
“Ilẹ Naijiria o le ni itẹsiwaju lai jẹ pe ijọba ṣe atunṣe gbogbo to yẹ, ohun ti Oluwa sọ pe ọna abayọ si iṣoro Naijiria jẹ niyẹn, ki i ṣe eto idibo. Ti wọn o ba ṣe e ni kiakia bayii, orilẹ-ede yii le da wo, ohun ti a o lero rẹ yoo si ṣẹlẹ”.
Nigba to n sọrọ lori wahala tuntun tawọn ọmọ Naijiria tun fẹẹ tọrun wọn bọ, Ayọdele ni ko si eyikeyii ninu awọn oludije dupo aarẹ ti yoo yanju iṣoro orile-ede yii, nitori irọ ni gbogbo ipolongo ibo ti wọn n ṣe kiri. O fi kun un pe lojuna ati mu Naijiria wa ni iṣọkan, afi ki wọn ṣatunṣe gbogbo to yẹ.