Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ẹgbẹ kan ti wọn pe orukọ ara wọn ni Osinbajo Volunteers Group (OVG) ti lẹ posita Igbakeji aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, kaakiri awọn ibi to ṣe koko niluu Oṣogbo.
Gbogbo agbegbe ti akọroyin wa gba kọja bii Lameco, Oke-Onitea, Dele Yes Sir, Garaaji Ileṣa, Oke-Baalẹ, Orita Ọja-Ọba, Gbodofọn, Orita-Gbaẹmu, Old Garage, Abere ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn lẹ posita naa mọ.
Ninu iwe naa ni wọn ti sọ pe gbogbo eeyan ni Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo wa fun lọdun 2023 (Osinbajo For All, 2023)
ALAROYE ba ọkan lara awọn ti wọn n lẹ iwe naa kaakiri, Peter Ogundeji Apata sọrọ. O ṣalaye pe oun ni alaga ẹgbẹ OVG to n polongo Osinbajo kaakiri.
O ni ko sẹni to gbeṣẹ ran awọn, bẹẹ ni Ọṣinbajo ko ran awọn niṣẹ rara, ṣugbọn awọn gẹgẹ bii ọdọ atawọn agbaagba lọkunrin ati lobinrin jokoo, awọn si kiyesi igbesi aye Osinbajo, bẹẹ lawọn ri i pe o kunju oṣunwọn lati dupo aarẹ orileede yii.
Apata sọ siwaju pe kaakiri orileede yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ OVG wa, ti awọn si ti pinnu lati maa fọnrere orukọ Ọṣinbajọ kaakiri nitori o kaato lati ko awọn ọmọ orileede yii delẹ ileri labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn ba fa a kalẹ lọdun 2023.
Apata fi kun ọrọ rẹ pe awọkọṣe rere ni Ọṣinbajo jẹ fun awọn ọdọ lorileede yii, awọn si ti pinnu lati maa lọ kaakiri lati le jẹ ki awọn ọmọ orileede yii tubọ mọ awọn amuyẹ to ni gẹge bii aṣiwaju rere.