Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii lọwọ, afaimọ ki Feyiṣọla Dosumu, ogbologboo apaayan to n ṣa wọn pa l’Ogere, nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ, ma ti jẹ Ọlọrun nipe, nitori ọwọ awọn ọlọpaa ti ba a, a si gbọ pe wọn ṣina ibọn fun un nigba to fẹẹ sa lọ.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi, alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, wulẹ ti fidi ẹ mulẹ fun ALAROYE pe ọwọ awọn ti ba Spartan to ti pa ju eeyan mẹfa lọ lawọn agbegbe bii Ogere ati Ipẹru.
Nnkan bii aago kan ọsan oni, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu kẹjọ lọwọ ba a gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
Ṣugbọn ṣaaju kọwọ too ba ogbologboo apaayan yii, o ti kọkọ ṣa baba kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọlatunji Ọladeji pa ladugbo Oluwatẹdo, l’Ogere.
Ẹni ọdun mẹtalelaaadọta(53) ni ọkunrin ti wọn ni Feyiṣọla ṣa pa yii, niṣe lo si n dari pada sile lati ibi iṣẹ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ yii, to fi bọ sọwọ Spartan to si ṣa a pa.
Wọn gbe Alagba Ọladeji lọ sọsibitu ninu agbara ẹjẹ, ṣugbọn awọn dokita sọ pe o ti ku.
Iku baba yii lo tun mu ṣiṣọ ti awọn ọlọpaa n ṣọ agbegbe Ogere nipọn si i, ṣe latigba ti Spartan ti pa obinrin kan to n tọmọ lọwọ, ati baba ọlọdẹ kan losu to kọja yii ni awọn ọlọpaa ko ti fi agbegbe naa silẹ, wọn n ṣọ ibẹ loju mejeeji tọsan-toru ni.
ALAROYE gbọ pe awọn eeyan kan ri ọmọkunrin yii lanaa ọjọ Mọnde, to n rin kiri, awọn ọlọpaa naa ri i wọn si jọ wọya ija, nibẹ la gbọ pe wọn ti yin in nibọn, ati pe ibi ti ibọn naa ti ba a lagbara pupọ, yiye rẹ di ọwọ Ọlọrun ọba.
Feyiṣọla ni arun ọpọlọ gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn lo sa kuro ni Aro, nibi ti wọn ti n tọju awọn alaisan ọpọlọ ni. Ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni pẹlu nigba to wa nileewe gbogboniṣe MAPOLY, wọn lo n mu kisa ninu igbo, bẹẹ ni oogun oloro mimu ko jẹ nnkan kan fun un.
Kọwọ too ba a yii, awọn ọlọpaa ti kede ẹ pe awọn n wa a tipẹ. O ṣee ṣe ki Spartan, ku, o si ṣee ṣe ko ye, mejeeji dọwọ Ọlọrun Ọba