Awọn tọọgi kọ lu Atiku, eeyan mẹrinlelaaadọrin dero ọsibitu ni Borno

Faith Adebọla

Ko din ni eeyan mẹrinlelaaadọrin (74) ti wọn gbe digbadigba lọ si ọsibitu fun itọju pajawiri latari bawọn tọọgi kan ṣe ya bo ikọ ipolongo oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla yii, niluu Maiduguri, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Borno.

ALAROYE gbọ pe obitibiti ero ti wọn jẹ ololufẹ igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹri ọhun ni wọn tu yaaya jade, ti wọn si n pariwo Atiku ati PDP, wọn n fi idunnu wọn han, wọn si n ki oludije naa kaabọ.

Ikọ ipolongo naa kọkọ kọja si aafin Shehu ilu Borno, lati ba ọba alaye ilu naa fikun lukun, lẹyin ti wọn jade nibẹ, ti wọn kọri si gbagede igbalejo Ramat Square, nibi tawọn alatilẹyin wọn ti n duro de wọn, ni akọlu naa waye.

Wọn ni niṣe lawọn janduku kan gbiyanju lati di wọn lọna, wọn bẹrẹ si i lẹ mọto wọn loko, wọn fa igi, ada, aake, atawọn nnkan ija mi-in yọ si wọn, wọn bẹrẹ si i ṣakọlu si ọkọ wọn, wọn n fọ gilaasi, wọn si n lu awọn eeyan, ṣugbọn awọn ololufẹ PDP naa ko kawọ lẹran o, ọrọ ọhun si di yanpọnyanrin.

Ọpẹlọpẹ awọn agbofinro to wa pẹlu ikọ naa, iṣẹ aṣelaagun ni wọn ṣe ki wọn too dẹrọ wahala ọhun, nigba ti eruku ija naa yoo si fi rọlẹ, eeyan rẹpẹtẹ lo ti fara ṣeṣe, bọọsi ati ọkọ ayọkẹlẹ mẹwaa ni wọn bajẹ, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ku.

Agbẹnusọ fun ikọ ipolongo Atiku, Sẹnetọ Dino Melaye, toun naa wa nibi iṣẹlẹ yii sọ pe ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) lo wa nidii akọlu ọhun, o ni niṣe ni wọn fẹẹ diidi dabaru eto ipolongo ibo awọn, ṣugbọn “a fẹẹ fi da wọn loju pe ko sohunkohun ti wọn le ṣe to maa da wa duro.”

A gbọ pe gẹrẹ ti Atiku pari eto naa ti ikọ ipolongo rẹ jade niluu ọhun ni ọkọ panapana to jẹ tijọba waa tu omi jade soju titi, tawọn eeyan kan ti wọn mu asia APC dani si n fi igbalẹ gba omi naa danu, gẹgẹ bii ami pe wọn fọ ipasẹ awọn Atiku atawọn alatilẹyin kuro lọna wọn.

Leave a Reply