Oke aja ni wọn ti mu Timilẹyin to ji ọkada Joseph gbe

Gbenga Amos, Ogun

Ọjọ gbogbo ni t’ole, ọjọ kan ni tolohun, bi Yoruba ṣe n powe. Ilẹ ọjọ kan ọhun mọ ba afurasi adigunjale kan ti wọn porukọ ẹ ni Timilẹyin Abayọmi lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nigba tọwọ awọn ẹṣọ alaabo so-safe tẹ ẹ lẹyin to fọ fẹnsi ile Ọgbẹni Taiwo Joseph, to si ji ọkada Bajaj ọkunrin naa gbe sa lọ.

Gẹgẹ b’Alukoro ẹṣọ alaabo so-safe, Moruf Yusuf, ṣe sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE l’Ọjọruu, ọjọ Wẹsidee, ọsẹ yii, o ni iṣẹ agbero ni Timilẹyin loun n ṣe, ọkan ninu awọn ẹgbẹ onimọto loun n ba ṣiṣẹ lagbegbe Owode, ilu naa si loun n gbe, ni adugbo ti wọn n pe ni Alagbọn, nijọba ibilẹ Guusu Yewa.

Adugbo Idaba, ni Ilaṣẹ, ni ile Joseph tadigunjale yii fọ wa, wọn ni bo ṣe gbẹyin wọle naa, taara lo kọja si ẹyinkule, nibi tọkunrin naa maa gbe ọkada rẹ si, o ja kọkọrọ ti wọn fi ti ọrun ọkada naa, lo ba gbe e sa lọ.

Ilu Ilaṣẹ ọhun naa lọwọ ti to jagunlabi, ṣugbọn oju bọrọ kọ ni wọn ri i mu, wọn ni bo ṣe ri awọn ẹṣọ alaabo so-safe lo ti fura pe oun ni wọn n wa bọ, lo ba fere ge e, awọn naa si gba, wọn fi ya a, lojiji ni wọn lo ya bara si ile awọn ẹni ẹlẹni kan, o ta mọ oke aja ile wọn, o fọ silin (ceiling) ile naa, inu yara oniyara to balẹ si ni wọn ka a mọ, ni wọn ba gbe e.

O ti mu wọn debi to gbe ọkada to ji naa si, o loun ṣẹṣẹ n wa ọna lati gbe e jade lọọ sibi to fẹẹ ta a si ni.

Yusuf lawọn ti fa ọkunrin naa le awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ Idiroko lọwọ, pẹlu ọkada to ji, ki wọn le tubọ ṣe iwadii lori ẹ, ki wọn si foju ẹ bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply