Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọkunrin kan to maa n fi ọrọ bibani ṣeto irinajo lọ si ilẹ okeere ṣe gbaju-ẹ fawọn eeyan, Alhaji Nurudeen Adebayo, ẹni ọdun mejilelogoji, ni ajọ sifu difẹnsi ti mu bayii nitori jibiti miliọnu mẹtala to lu awọn eeyan kan.
Alukoro ajọ naa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Afọlabi Tolulopẹ, sọ pe ọkunrin to fi ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ṣebugbe yii, lọwọ tẹ lẹyin to ti fi ọgbọn jibiti gba owo to to miliọnu mẹtala lọwọ awọn to fẹẹ rin irina-ajo lọ si Mecca ati Jerusalemu, nipinlẹ Ekiti, Ondo ati Ọsun.
ALAROYE gbọ pe lọdun 2020 ati 2021 ni Alaaji yii gba owo to pọ lọwọ awọn Musulumi ti wọn fẹẹ rin irin-ajo lọ si Saudi, ti ko si ba wọn ṣeto kankan lẹyin to ti gbowo lọwọ wọn.
Niṣe lọkunrin yii sa lọ, to si paarọ nọmba ẹrọ ilewọ rẹ, ti ẹnikẹni ko ri i pe mọ.
O ṣalaye pe ni kete ti wọn fi ẹsun naa to ẹka to n gbogun ti iwa jibiti lilu leti ni wọn ti bẹrẹ igbesẹ lati mu un. Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lọwọ ti pada tẹ ẹ, ti wọn si gbe e pada wa si Ekiti.
Tolulọpe ni ọdaran naa ti jẹwọ pe loootọ loun ṣẹ ẹṣẹ naa, o si ti n ran ajọ ọhun lọwọ lori iwadii wọn. O ni ni kete tawọn ba ti pari iwadii lawọn yoo gbe e lọ sile-ẹjọ.
Ninu iroyin mi-in, ajọ yii tun kede pe ọwọ awọn tẹ eeyan meji ni Isẹ-Ekiti, nijọba Ibilẹ Isẹ/Ọrun.
Alukoro ajọ sifu difẹnsi sọ pe awọn ọdaran naa, Kayọde Ilesanmi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), ati Samson Ọmọtayọ, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), lọwọ tẹ niluu Isẹ-Ekiti pe wọn n gbe oogun oloro. O ni ni kete ti wọn ta ajọ naa lolobo pe awọn oniṣowo egboogi oloro kan ati awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun wa loju ọna to lọ lati Iṣẹ si Ikẹrẹ-Ekiti lawọn lọ sibẹ.
O ni o gba awọn oṣiṣẹ ajọ naa ni wahala ki wọn too ri wọn mu pẹlu bi awọn ọdọ ilu ọhun ṣe di gbogbo ọna to wọ ilu yii pa, ti wọn ko fẹ ki wọn wọle. Ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ wahala, wọn ri wọn mu.
A gbọ pe ọkan lara awọn ọdaran naa, Kayọde Fagbamigbe, jẹ akẹkọọ nileewe giga yunifasiti kan ni orileede Tanzania. Ṣugbọn o wa si orilẹ-ede Naijiria lati waa ra egboogi igbo, nigba ti Samson Ọmọtayọ jẹ agbẹ to n gbin igbo ni tiẹ.
Awọn mejeeji lo ni wọn ti wa ni akata ajọ sifu difẹnsi, ti iṣẹ si n lọ lọwọ lati ri awọn yooku mu. O fi kun un pe ni kete tawọn ba ti pari iwadii lori ọrọ wọn ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.