‘Ki n le ko arun HIV ti mo ni ran ọpọ eeyan ni mo ṣe maa n fa ẹjẹ mi sinu sobo ti mo n ta’

Monisọla Saka

Kayeefi ati iyalẹnu gbaa lọrọ obinrin kan to jẹwọ pe oun ni arun kogboogun ti wọn n pe ni HIV, ṣugbọn oun ti pinu pe oun nikan kọ loun yoo maa ru arun naa kiri, afi ki oun tun pin in fun awọn ẹlomi-in, nitori oun nikan kọ loun maa ku nitori aisan buruku yii. Eyi lo mu ki obinrin naa pinnu lati maa fi ẹjẹ rẹ to ti ni arun kogboogun yii sinu sobo, ohun mimu to gbajumọ daadaa tobinrin naa n ta, to si n ta a fun awọn eeyan, leyii to ṣee ṣe ki ọpọ ti ko arun yii latara igbesẹ obinrin yii.

Lalẹ Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla yii, ni obinrin ti ẹnikẹni ko mọ naa pe wọle sori eto ori redio kan ti wọn n pe ni MarketRunz, eyi to tumọ si gbogbo ọgbọn ati ete tawọn oniṣowo n lo ninu ọja, ṣugbọn ti awọn naa mọ pe ko dara, lori ikanni redio Wazobia FM.

Nibẹ lobinrin naa ti sọ pe “Ki n ma parọ, nigba ti mo lọ si ile iwosan ni nnkan bii oṣu mẹfa sẹyin, esi ayẹwo ti wọn ṣe fun mi jẹ ki n mọ pe mo ti lugbadi arun kogboogun ti wọn n pe ni HIV. Igba ti ko si ti si owo ti mo le fi maa tọju ara mi nibi kankan ni mo fi ro o pe emi nikan kọ ni mo maa da ku. Eyi ni mo ro ti mo fi bẹrẹ si i da ẹjẹ mi sinu zobo ti mo n ta, ti mo si n ta a fun ọpọ eeyan mu.

“Abẹrẹ tawọn nọọsi n lo ni ọsibitu ni mo fi maa n fa ẹjẹ mi, lẹyin naa ni mo maa po o pọ mọ zobo. Eyi rọrun fun mi nitori pe nọọsi alabẹrẹ ni mi tẹlẹtẹlẹ, nigba ti dokita sọ fun mi pe mo ti ni HIV ni mo fiṣẹ silẹ. Inu mi ko dun si nnkan ti mo n ṣe yii, ṣugbọn inu mi tun dun nidakeji pe emi nikan kọ ni ma a ku”.

Bẹẹ lobinrin naa jẹwọ lori eto to pe si. Ọlọrun nikan lo mọ ibi to n gbe ati iye awọn eeyan to ti ṣe bẹẹ fowo wọn ra majele jẹ lọwọ ọdaju ẹda bẹẹ.

Olootu eto naa lo da ọrọ yii silẹ lasiko to ni ki awọn araale ti wọn n gbọ eto naa pe wọle sori eto, ki wọn si jẹwọ awọn iwa eeri ti wọn ti hu ninu ọja ri, ṣugbọn tawọn eeyan ko mọ, ti ki i si i ṣe ohun amuyangan tabi iwuri fun awọn gan-an alara.

Leave a Reply