Gbenga Amos, Ogun
Ni wara-n-ṣe-ṣa, bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii, ẹni to ba pe ileewe ẹkọṣẹ tiṣa Tai-Ṣolarin College of Education to wa l’Omu-Ajọsẹ, n’Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun, lorukọ naa, tabi to pe e ni TASCE gẹgẹ bii ikekuru orukọ rẹ tawọn eeyan mọ daadaa, agbọnrin eṣi ni onitọhun n jẹ l’ọbẹ niyẹn, ko sohun to n jẹ orukọ naa ati inagijẹ ọhun mọ lọdọ ijọba, wọn ti yi orukọ naa pada, igbega si ti de ba ileewe giga ọhun, orukọ rẹ tuntun ni: Sikiru Adetọna College of Education, Science and Technology, tabi SACOETEC.
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lo kede ayipada yii lọjọ Tusidee ọhun, nibi ayẹyẹ akanṣe kan to waye lati fi bu ọla fun Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna, niluu Ijẹbu-Ode.
Lasiko to n ṣiṣọ loju eegun orukọ tuntun naa, Abiọdun ni iṣakoso oun ko ni i kuna lati ṣe gbogbo nnkan to ba yẹ ni ṣiṣe ki ileewe naa le tubọ kunju oṣuwọn lati figa-gbaga pẹlu awọn kọlẹẹji bii tiẹ lorileede yii.
O ni bo tilẹ jẹ pe ileewe naa yoo maa da awọn akẹkọọ lẹkọọ, ti yoo si maa fun wọn niwee-ẹri digirii, sibẹ yoo ṣi maa kọ awọn olukọni, awọn tiṣa, lati di alafo to wa fun ipese awọn olukọ nipinlẹ naa, o nidii eyi lawọn o ṣe ku giri yii ileewe naa pada si fasiti tabi ileewe gbogboniṣe.
“A maa ṣatilẹyin fun kọlẹẹji yii pẹlu ipese awọn ohun amayedẹrun. Ẹ wo o, laipẹ laijinna, a maa ṣi ọna igboro to lọ lati ileewe yii si Ala, eyi to gba Omu kọja,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Gomina naa ni ilẹ Ijẹbu ti laasiki gidi lasiko iṣakoso Awujalẹ yii, o si kan saara si ori-ade naa, o ni Ọba Awujalẹ yii lo ja fitafita lati ri i daju pe wọn ṣedasilẹ ẹka ti wọn ti n gba imọ nipa iṣejọba eyi to ba ti agbaye mu, iyẹn International Institute of Governance, silẹ ni fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, to wa l’Agọ-Iwoye.
O ni saa rere lawọn araalu mọ igba Awujalẹ si, tori o lo ipo rẹ lati fa awọn oludaṣẹ-ṣilẹ wa sagbegbe naa, ti wọn waa fidi okoowo atawọn ileeṣẹ nla nla mulẹ n’Ijẹbu. O ni idi eyi lawọn fi pinnu lati fi orukọ kabiyesi naa sara awọn nnkan aritọkasi ti yoo mu ki orukọ naa wa ninu iranti titi aye.
Abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, ki gomina lẹyin, o ni ko sirọ ninu ọrọ ti gomina sọ nipa Awujalẹ, eyi lo si fa a to fi jẹ pe ko sẹnikẹni to ta ko abadofin ti wọn fi yi orukọ kọlẹẹji naa pada lati TASCE si SACOETEC, nigba tawọn n ṣe agbeyẹwo rẹ nileegbimọ aṣofin wọn, o ni ika to tọ simu nijọba ipinlẹ Ogun fi ro’mu lori ayipada orukọ naa.
Nigba to n fesi, Ọba Sikuri Adetọna ni inu oun dun jọjọ si apọnle, iyi ati ẹyẹ ti wọn ṣe foun loju aye oun yii. O lọmọ-ọkọ atata ni Dapọ Abiọdun, iṣejọba rẹ si tu ilu lara, eyi ni gomina naa fi di ẹni-aye-nfẹ nipinlẹ Ogun.
O waa mu un da gbogbo eeyan loju pe wiwọle Abiọdun fun saa keji lasiko ibo 2023 to n bọ yii ko l’ẹja n b’akan ninu rara, Ifa maa fọre fun DA ni, gẹgẹ inagijẹ rẹ.