TOM gba Adeleke nimọran: Tẹsiwaju ninu awọn eto rere tijọba Oyetọla ba ṣe

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ kan ti ki i ṣe tijọba, The Osun Masterminds, ti gba gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, niyanju lati ma ṣe da gbogbo awọn eto to dara ninu iṣejọba ẹni to fẹẹ gbaṣẹ lọwọ rẹ, Gomina Adegboyega Oyetọla, nu.

Nigba ti alakooso ẹgbẹ naa, Dokita Wasiu Oyedokun-Alli, n ba awọn oniroyin sọrọ laipẹ yii lo woye pe ti eeyan yoo ba sọ tootọ, iṣejọba ti Adeleke fẹẹ gba iṣẹ lọwọ rẹ jẹ eyi to ṣọwo na, ti ko ṣe owo ilu baṣubaṣu laarin ọdun mẹrin to fi wa nibẹ.

Oyedokun-Alli sọ siwaju pe ki gomina tuntun yii tete pakiti mọra nipa mimu igbelarugẹ ba eto ọrọ-aje ipinlẹ Ọṣun nipasẹ iṣẹ agbẹ ati awọn ibudo igbafẹ to wa kaakiri.

O ni lara awọn eto rere tijọba Oyetọla n ṣe nipinlẹ Ọṣun, to si yẹ ki Sẹnetọ Ademọla Adeleke tẹra mọ ni aifaaye gbe inakunaa ati riri i daju pe wọn na owo to ba n wọle si ọna to tọ.

“Bakan naa, Ademọla Adeleke ko gbọdọ faaye gba awọn ọlọtẹ layiika rẹ, tabi ero kankan to le mu un pinnu lati fagi le awọn eto to n ṣe awọn araalu lanfaani lara awọn eto tijọba Oyetọla n ṣe.

“Ijọba n tẹsiwaju ni, nitori naa, awọn eto rere gbọdọ tẹsiwaju. A tun n gba gomina tuntun niyanju lati ri i pe oun ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu awọn aṣofin ti yoo ba nileegbimọ pẹlu bo ṣe jẹ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo pọ ju lara wọn.”

TOM gboṣuba fun Gomina Gboyega Oyetọla fun iṣẹ takuntakun to ṣe nipinlẹ Ọṣun lai fi ti obitibiti gbese to ba nilẹ nigba to de ṣe, wọn si rọ ọ lati ri i pe gbigbe eeku ida iṣejọba le gomina tuntun lọwọ lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

Bakan naa ni wọn ke si awọn alatilẹyin Sẹnetọ Ademọla Adeleke lati mọ pe gomina wọn ki i ṣe fun ẹgbẹ oṣelu PDP nikan, bi ko ṣe fun gbogbo ipinlẹ Ọṣun, nitori naa, wọn ko gbọdọ faaye gba wahala kankan ṣaaju, lasiko ati lẹyin ibura ti yoo waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Leave a Reply