Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ti sọko ọrọ si gomina ana ati igbakeji rẹ, Alhaji Gboyega Oyetọla ati Benedict Alabi, lori bi gbogbo ile ijọba ṣe wa ni korofo lẹyin ti wọn kuro nibẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Ninu fidio to n ja ran-in kaakiri ori ayelujara ni wọn ti sọ pe gbogbo nnkan to wulo patapata ninu ile ti Oyetọla gbe ni wọn ko kuro.
Wọn ni gbogbo ẹrọ amomitutu, aga, timutimu, ati gbogbo nnkan to wa ninu ile idana gomina, to fi mọ isaasun, ṣibi ọbẹ ati oniruuru nnkan mi-in ni wọn ti ko lọ patapata.
Koda, ninu ile ti igbakeji gomina gbe, wọn tu tẹlifiṣan ara ogiri, bẹẹ ni wọn tu awọn nnkan mi-in to n lo ina nibẹ.
Nigba to n ṣọrọ lori iṣẹlẹ naa, Agbẹnusọ fun Gomina Ademọla Adeleke, Ọlawale Rasheed, sọ pe ohun idojuti nla gbaa ni ki ojukokoro ba awọn oloṣelu debii pe wọn yoo sọ ile ijọba di korofo ki wọn too kuro nibẹ.
Ọlawale ṣalaye pe igbimọ kan ti gomina gbe kalẹ lati ṣewadii dukia ijọba yoo le awọn to ṣiṣẹ laabi naa ba, wọn yoo si gba gbogbo ẹru ijọba to wa ni sakani wọn.
Amọ nigba to n fesi si ẹsun naa, kọmiṣanna fun Gomina Oyetọla lori eto iroyin, Funkẹ Ẹgbẹmọde, sọ pe ọrọ apara ati ọrọ ẹrin ni igbe ti awọn ẹgbẹ oṣelu PDP n ke kaakiri yii jẹ.
Ẹgbẹmọde ṣalaye pe gbogbo igbesẹ ti ẹgbẹ PDP n gbe ni lati ba orukọ Gomina Oyetọla jẹ dandan, ṣugbọn ẹni to ba ni laakaye yoo ro o lẹẹmeji ohun to le mu gomina to tun gbogbo ilegbee ijọba ṣe loṣu Kẹfa, ọdun yii, tun maa ko ẹru inu ẹ.
O ni lati ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni alakooso ile ijọba ti kọ lẹta si ajọ Sifu Difẹnsi lori bi awọn ‘ole’ kan ṣe n lọọ ko ẹru ijọba ni kọtaasi naa latigba ti gomina ati igbakeji rẹ ti kuro nibẹ.
O ke sijọba tuntun lati gbajumọ awọn nnkan to le mu aye rọrun fawọn araalu, iru eyi tijọba Oyetọla ṣe, nitori pe igba lonigba n ka.