Awọn agbebọn ji alufaa ijọ Katoliiki gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn agbebọn tun ṣoro nipinlẹ Ekiti pẹlu bi wọn ṣe ji alufaa ijọ Katoliiki kan, Rev. Fr. Micheal Olubunmi Ọlọfinlade, gbe loju ọna Itaji-Ekiti si Ijẹlu-Ekiti, nipilẹ Ekiti.

Alufaa ti wọn ji gbe yii lo n dari ijọ St George Catholic Church, Omuo-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ, nipinlẹ naa.

ALAROYE gbọ pe iṣẹ Oluwa lo gbe iranṣẹ Ọlọrun naa kuro ni ilu Omuo-Ekiti lọ si Akurẹ. Nigba to ṣe ohun to fẹẹ sẹ tan lọhun-un to n pada lọ si ibi to ti wa lawọn agbebọn yii da a lọna, ti wọn si wọ ọ jade ninu ọkọ rẹ, ni wọn ba wọ ọ wọnu igbo lọ.

A gbọ pe awọn Amọtẹkun ti n tu gbogbo inu igbo to wa nitosi ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ lati gba iranṣẹ Ọlọrun naa silẹ.

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, wọn ko ti i kan si mọlẹbi tabi ijọ ti ọkunrin naa n dari lati beere owo itusilẹ kankan.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn agbebọn kan naa lọọ ka alufaa ijọ Katoliiki kan mọle ni ipinlẹ Niger. Nigba ti wọn wa gbogbo ọna lati wọnu ile rẹ ti wọn ko ri i ni wọn ni dana sun alufaa naa mọnu ile.

Leave a Reply