Faith Adebọla
A ki i sọ fọmọde pe ko ma ṣe dẹtẹ, to ba ti le da inu igbo gbe, owe yii lo ṣẹ mọ ọdọmọkunrin kan, Sharafadeen Oyeyẹmi, ẹni ti adajọ ti ni ko lọọ faṣọ pempe roko ọba fun ọdun marun-un. Boya ijiya naa iba iba tiẹ gun ju bẹẹ lọ, amọ latari bo ṣe fẹnu ara ẹ jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun gbigbe egboogi oloro tijọba ti ka leewọ, to si rawọ ẹbẹ si adajọ pe ki wọn fi eyi fa oun leti, oun o tun jẹ sanṣọ iru ẹ ṣoro mọ, ni wọn fi la a mọ gbaga.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta yii, nidajọ naa waye nile-ẹjọ giga to n gbọ awọn ẹsun akanṣe, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Ajọ to n gbogun ti okoowo ati ilo egboogi oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency, NDLEA, lo wọ ọdaran naa lọ ile-ẹjọ pẹlu ẹsun mẹta ọtọọtọ, wọn lo n ko egboogi oloro tramadol, rophynol ati ọkan ti wọn pe ni ecstasy, 4-methylenedioxy ati N-methamphetamine ni wọn lo wa ninu egboogi yii, ko si bofin mu, tori niṣe lo maa n pa awọn ti wọn ba lo o lọbọlọ, tabi ki ori wọn gbona sodi.
Nigba ti Agbefọba, Ọgbẹni Augustine Nwagu, n sọrọ lori ẹsun yii ni kootu, o ko awọn egboogi oloro ti wọn ka mọ ọdaran ọhun lọwọ siwaju adajọ, wọn lẹ orukọ ọkọọkan wọn mọ ọn, o si ṣalaye pe awọn ti lọọ ṣayẹwo, awọn si ti fidi ẹ mulẹ pe ẹru ofin ni wọn.
O ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ NDLEA ni wọn mu Sharafadeen yii lọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lasiko ti wọn n ṣayẹwo sawọn ẹru to fẹẹ ko wọ baaluu ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, n’Ikẹja, ilu Dubai ni wọn lo fẹẹ kẹru ofin ọhun lọ tọwọ fi tẹ ẹ.
Nigba tọrọ kan olujẹjọ, o loun ko ni awijare kan lati ṣe mọ, o ni loootọ loun ṣe okoowo egboogi oloro naa, oju owo to n kan oun lo jẹ koun lọwọ si iwa irufin naa, oun ko si ni i sanṣọ iru ẹ ṣoro mọ, ki wọn fori ji oun.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Chukwujeku Aneke sọ pe ẹri to wa niwaju oun pẹlu ẹsibiiti ti wọn fi gbe e lẹsẹ yii, ati bi olujẹjọ ti ṣe fẹnu ara ẹ jẹwọ pe loootọ loun ṣe lodi sofin, o ni ọrọ rẹ ko la ẹnikẹni looogun mọ, ilẹ-ẹjọ ti fidi ẹ mulẹ pe o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Adajọ ni ko lọọ ṣẹwọn ọdun marun-un marun-un fun ẹsun kọọkan, eyi ti aropọ rẹ jẹ ẹwọn ọdun mẹẹdogun. Amọ, o ni ẹẹkan naa ni yoo ṣẹwọn ọhun papọ, to tumọ si pe ọdun marun-un ni yoo fi jẹwa lọgba.
Adajọ ni ti ko ba si fẹẹ ṣẹwọn, ko lọọ san owo itanran miliọnu marun-un Naira sapo ijọba.