‘Emi ni mo ṣa akẹkọọ fasiti yii pa nitori mo ti fowo to ni ki n fi b’oun wale ta tẹtẹ’

Ọrẹoluwa Adedeji

Epe rabandẹ rabandẹ lawọn eeyan n gbe ọkunrin abaniwale kan, Shagbaor Ugosor Japhet ṣẹ pẹlu bo ṣe pa akẹkọọ to wa ni ipele kẹta nileewe gioga Yunifasiti Benue, nipinlẹ Benue, lẹyin to gba ẹgbẹrun lọna adọjọ Naira (150, 000) lọwọ rẹ pẹlu adehun pe oun yoo ba a wale, ṣugbọn ti ko mu adehun naa ṣẹ, bẹẹ ni ko da owo akẹkọọ torukọ rẹ n jẹ Erekaa Dooshimaa pada. Eyi ti awọn eeyan si maa gbọ ni pe o tan ọmọbinrin naa lọ sibi kan, o si fada ṣa a yanna yanna titi to fi ku, lẹyin naa lo wọ oku rẹ ju sẹgbẹẹ igbo.

Laipẹ yii tọwọ tẹ ọmọkunrin naa lo jẹwọ fawọn ọlọpaa bo ṣe ṣeku pa akẹkọọ ti wọn ni ko ti i ju bii ọdun meji lọ ti baba rẹ jade laye ọhun lọ.

Japhet ṣalaye fawọn agbofinro pe loootọ ni ọmọbinrin naa waa ba oun pe oun nilo ile niwọn igba to jẹ iṣẹ abaniwale loun n ṣẹ. O ni awọn dunaadura si ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira. Dooshima si fi owo naa ranṣẹ si ohun lati ọdọ oni POS kan.

Ṣugbọn niṣe ni oun fi owo to fun oun yii ta tẹtẹ, eyi ko si jẹ ki oun ri owo naa da pada fun un tabi ki oun ba a wa ile ti oun ṣeleri lati ba a wa. ‘‘Nigba ti mi o ri ọna lati da owo naa pada ni mo ranṣẹ si ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn naa pe ko wa. Nigba to de ibi kọrọ kan to ṣokunkun ninu siriiti ti mo ti ni ko waa ba mi ni mo ṣa a ladaa lọpọlọpọ igba, eyi to mu ki ọmọbinrin naa ku.

‘‘Lẹyin ti mo pa a tan ni mo gbe oku rẹ pẹlu iPhone rẹ, ti mo si ju oku rẹ si ẹgbẹ ọna ni agbegbe naa ko le baa da bii pe awọn kan ni wọn pa a’’. Ṣugbọn awọn ọlọpaa pada lọọ gba akanti ọmọbinrin yii ni banki, oun ni wọn ṣayẹwo si ti wọn fi ri i pe o sanwo fun ọmọkunrin naa pẹlu ẹrọ POS, eyi ni awọn ọlọpaa ri ti wọn fi lọọ gbe Japhet, o si jẹwọ pe loootọ, oun loun pa akẹkọọ Yunifasiti Benue to wa ni ọdun kẹta nileewe giga yunifasiti yii.

Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni wọn n wa ọmọbinrin naa ti ẹnikẹni ko si mọ bo ṣe rin. Leyin ọjọ kẹta ti wọn ti n wa a ni wọn ba oku rẹ, foonu rẹ ati kaadi idanimọ rẹ pẹlu ẹjẹ ati ọgbẹ kitikiti lara rẹ nitosi Rahama Clinic, to wa ni adojukọ Medical School, ni agbegbe Brewery Qarters, niluu Markurdi, nipinlẹ Benue, lọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun yii.

Ṣa ọmọkunrin to pa akẹkọo yii ṣi wa ni akata awọn agbofinro, nibi to ti n ran wọn lọwọ lori iwadii ti wọn n ṣe nipa iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply