Monisọla Saka
Ijọba ipinlẹ Jigawa ti din iye akoko tawọn oṣiṣẹ ijọba fi n ṣiṣẹ nipinlẹ naa ku pẹlu wakati meji, pẹlu bi aawẹ Ramadan ọdun 2023 ṣe gbera sọ.
Ninu atẹjade ti Olori oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Hussaini Kila, fi sita lati ọwọ Alukoro ileeṣẹ naa, Ismail Dutse, ni wọn ti sọrọ yii di mimọ niluu Dutse, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bi ohun to wa ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, aago mẹsan-an aarọ ni wọn lawọn oṣiṣẹ yoo maa de ẹnu iṣẹ wọn, ti wọn yoo si maa ṣiwọ iṣẹ laago mẹta ọsan, lati ọjọ Aje, Mọnde, si Ọjọbọ, Tọsidee, dipo aago marun-un ti wọn n ṣiwọ iṣẹ tẹlẹ.
O ni, “Lawọn ọjọ Ẹti, Furaidee, bakan naa, aago mẹsan-an aarọ ni wọn yoo maa wọṣẹ, ṣugbọn ti wọn yoo maa lọ sile wọn laago kan ọsan”.
O tẹsiwaju pe awọn ṣe eleyii lati fun awọn oṣiṣẹ laaye lati le ribi palẹmọ fun iṣinu, ki wọn si tun le raaye ṣe awọn iṣẹ laada loriṣiiriṣii ninu oṣu mimọ yii.
Ijọba ni igbagbọ awọn ni pe awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa yoo lo akoko gbigbadura yii lati beere fun itọsọna ati ibukun Ọlọrun fun ipinlẹ naa. Wọn yoo si tun lo anfaani akoko aawẹ yii lati gbadura fun alaafia ati eto ọrọ aje to gbooro fun ipinlẹ yii ati ilẹ Naijiria ni lapapọ.