Olori ẹṣọ Amotẹkun nipinlẹ Ekiti, Ọgagun Joe Kọmọlafẹ, ti ke sawọn ọba alaye lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹṣọ alaabo ọhun, ki wọn le ṣaṣeyọri nipinlẹ naa.

Kọmọlafẹ sọ pe gẹgẹ bi ipo awọn ọba alaye laarin ilu, ati bi wọn ṣe sun mọ araalu si, yoo fun wọn lanfaani lati pese eto aabo to yẹ.

Bakan naa lo ti rọ awọn araalu paapaa lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ ọhun nipa tita wọn lolobo lasiko to ba yẹ, paapaa ni kete ti wọn ba ti ṣakiyesi ohun to le ko wahala ba alaafia wọn laduugbo wọn.

O ni, olobo ti wọn ba n ta ẹṣọ Amọtẹkun lasiko to ba yẹ ko ni i ṣai ran awọn ẹṣọ wa lọwọ lati pese aabo to ba yẹ fun wọn lagbegbe wọn.

Kọmọlafẹ ninu ọrọ ẹ fun ọdun tuntun, eyi to fi ranṣe si awọn janduku ti wọn n da ipinlẹ naa laamu ni pe ki wọn tete gba ibomi-in lọ, nitori ẹṣọ Amọtẹkun ti ṣetan bayii lati mu ipinlẹ naa gbona girigiri fun wọn.

Kaakiri ipinlẹ Ekiti lo sọ pe awọn ẹṣọ ọhun wa bayii, lati mu eto aabo fẹsẹ rinlẹ daadaa pelu ajọṣepọ awọn ẹṣọ agbofinro mi-in. Bakan naa lo ti ke si awọn ọba alaye, awọn araalu, fun ifọwọsowọpọ wọn, ki iṣẹ ti awọn gbe lọwọ yii le so eso rere.

Leave a Reply